Kò dín ní ogún èèyàn àti oͅkòͅ 30 tó jóná nínú ìbúgbàmù ní Kogi

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

O kere tan ogun eniyan ti gbeͅmi mi, ti oͅkoͅ to le ni oͅgboͅn si jona raurau, leͅyin ti oͅkoͅ agbepo gbina ni ipinleͅ Kogi.

Isͅeͅleͅ naa waye ni agbegbe Ochadamu, ni ijoͅba ibileͅ Ofu, ni ipinleͅ naa.

Awoͅn ti isͅeͅleͅ naa sͅoju woͅn sọ pe oͅpoͅloͅpoͅ awoͅn ti eͅmi woͅn loͅ si isͅeͅleͅ naa ni woͅn jona raurau.

Ede aiyede laarin awoͅn eͅsͅoͅ oju popo ati awakoͅ tirela lo da wahala sileͅ – Osͅojumikoro

Oͅkan ninu awoͅn ti isͅeͅleͅ naa sͅoju woͅn sọ fun awoͅn akoͅroyin pe ariyanjiyan laarin awoͅn osͅisͅeͅ eleto aabo ati awoͅn awakoͅ elepo ni opopona lo fa ijamba oͅkoͅ naa.

Wọn ni oṣiṣẹ alaabo kan lo yinboͅn lu oͅkoͅ agbepo meji, ti awoͅn akeͅgbeͅ reͅ si lo oͅkoͅ to gbe epo beͅntiro lati fi di oju oͅna to lo si Idah.

‘’Awoͅn eniyan kesi awoͅn agbepo naa lati gbe oͅkoͅ woͅn kuro ni oju popo amoͅ woͅn koͅ.’’

‘’Leͅyin naa ni oͅkoͅ to gbe eedu ti ijanu reͅ ko sͅisͅeͅ dara dara koͅlu oͅkoͅ agbepo ti woͅn gbe si oju oͅna naa, to si gbina.’’

Ibugbamu oͅkoͅ agbepo naa fa ina nla to soͅ to si gbeͅmi awoͅn eniyan ati oͅkoͅ loju popo.