Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pọkún ètò ààbò ní òpópónà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn nítorí ìjínigbé

Oríṣun àwòrán, Oyo Police Force
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ati Ogun ti kede igbesẹ wọn lati ṣe afikun si awọn ọlọpaa to wa ni opopona marosẹ Eko si Ibadan lati fi opin si bii awọn janduku kan ṣe kọlu awọn arin rinajo.
Ọpọlọpọ ikọlu lo ti waye ni lemọlemọ ni opopona lati bi ọsẹ melo diẹ sẹyin, ti wọn si tun ji ọpọ eeyan lọ pelu.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso fi ransẹ si awọn akọroyin, ni Kọmisọna ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adebowale Williams, ti pinnu lati ri pe oun fi opin si bi awọn janduku naa ṣe n sọsẹ lopopona naa.
Williams, ẹni to kọ wọ rin pẹlu akẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole lọjọbọ, lọ si opopona ọhun, fi ọkan awọn arin rinajo balẹ pe awọn ti pese awọn ọlọpaa ti yoo kun awọn ti tẹlẹ lati da bobo ẹmi ati dukia awọn arin rinajo.

Oríṣun àwòrán, Oyo Police Force
O ni ileeṣẹ ọlọpaa mejeeji ti fọwọsowọpọ lati koju ija si awọn ajinigbe ati awọn oni iwa ibajẹ miiran lopopona Sagamu-Sapade-Onigari.
“Di da bobo awọn arin rinajo lopopona yii ti di isẹ ileeṣẹ mejeeji, ti a si jọ sisẹ papọ lati ile awọn janduku kuro lori lopopona morosẹ yii.”
Williams wa rọ awọn eeyan lati ma ṣe foya nbitori pe awọn ileeṣẹ ọlọpaa ti balẹ kati fi opin si dunkoko awọn ajinigbe ọhun.
O tẹsiwaju pe awọn ti wa ni ayika agbegbe ọhun, ti awọn yoo si sisẹ pọ awọn figilante agbegbe naa lati fi opon si dunkoko naa
O ni inu awọn yoo dun ti awọn eeyan ba le ṣe iranwọ fun awọn nipa ki wọn fi iroyin ti yoo wulo ransẹ si ileeṣẹ ọlọpaa.

Oríṣun àwòrán, Oyo Police Force















