Darandaran kan rí ẹ̀wọ̀n he fún ẹ̀sùn jíjí màálù 61 nìpínlẹ̀ Oyo

Ọmọkunrin to n da maalu

Oríṣun àwòrán, other

Ileẹjọ giga to n joko niluu Ibadan ti ran darndaran kan, ti orukọ rẹ n jẹ, Abubakar Sidi, lọ ewọn ọdun marun un fun ẹsun ole jija.

Sidi, ẹni ọgbọn ọdun sọ fun ile ẹjọ pe oun jẹbi ẹsun ji jale maalu mọkanlelọgọta.

Nigba ti o n sọrọ, ọlọpaa Olufemi Omilana ni Sidi ji maalu mọkanlelọgọta ti apa owo rẹ to ọgbọn milọnu Naira laarin ọdun 2020 si ọsu kẹwaa ọdun 2022 lọwọ arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Abdullahi Sidi niluu Igbeti, ki ọwọ to pada tẹ ẹ ninu ọja Kara to wa niluu naa.

Nigba ti o gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Munirat Giwa Babalola ni ile ẹjọ yoo sanu Sidi bii o ṣe gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Ṣaaju ni olujẹjọ ti tọrọ fun aanu ile ẹjọ.

Babalola ni iwa ole jija ko tọ si ẹnikẹni lati ṣe nitori o lodi si ofin orilẹede Naijiria.

Nitori naa lo ṣe ni ki Abubakar Sidi lọ si ẹwọn ọdun marun-un.