Ìdẹ̀rùn yóò báwọn ọmọ Nàìjíríà, tí Tinubu bá di Ààrẹ - Aisha Buhari

Aya aarẹ orilẹede yii, Aisha Buhari ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe oun le fọwọ sọya lori iyansipo oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu.
Aisha Buhari ni iyansipo Tinubu yoo san pupọ awọn ọmọ orilẹede Naijria si rere.
O ni ọwọ eeyan dada ni Najiria wa, ti Tinuba ba di aarẹ lọdun 2023.
Aya aarẹ, ti Asabe Bashir, olori awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC soju fun, sọ eleyi nigba to n kopa ninu ifọrọwerọ kan niluu Abuja.
O ni itan bi Tinubu ṣe ṣe ijọba rẹ tẹlẹ nilu Eko ti fihan pe oun gan ni ipo naa tọsi ju nitori o ni oye ati ori pipe to n fi ṣe ijọba rẹ.
Aisha wa kesi oludije ọhun pe ko maṣe gbagbe awọn obinrin kete to ba ti di aarẹ orilẹede Niajiria.
Tinubu, jọọ fi awọn obinrin sinu gbimọ ti yoo ṣe agbatẹru alafia ni Naijiria - Aisha Buhari
“Mo ti ri iwe afojusun ti Tinubu fi lede lori bii yoo ṣe ṣe ijọba rẹ, eyi to si fi mi lọkan balẹ pe iṣejọba rẹ to ba di aarẹ lọdun 2023 yoo mu ọpọlọpọ ilọsiwaju de ba orilẹde Naijiria.
“Mo wa n rọ Oludije wa ko ri pe wọn mu awọn obinrin mọ awọn ọmọ igbimọ ti yoo maa ṣe agbatẹru alafia lorilẹede Naijiria
“Idi ni pe gbogbo agbaye lo mọ pe ọga ni obinrin jẹ ninu ki a pese alaafia, ilọsiwaju ati idagbasoke ni awujọ wa.”
Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ oselu APC kede Asiwaju Bola Ahmed Tinubu gẹgẹ bii ẹni to gbegba oroke ninu ibo abẹnu fawọn oludije sipo aarẹ ti yoo soju ẹgbẹ oselu naa lọdun 2023.
Tinubu lo ni ibo to pọju ninu eto idibo naa, to si fi idi awọn oludije yoku janlẹ ninu ibo abẹnu ọhun.















