Mo fẹ́ díje fún ipò àárẹ ní 2024 láti gbé ògo America dìde lẹ́ẹ̀kan sí i - Trump

Aarẹ orile-ede America nigba kan, Donald Trump ti kede pe oun ni erongba lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2024.

Trump

Oríṣun àwòrán, @Trump

Trump kede eyi lasiko to n ba awọn alatilẹhin rẹ sọ̀rọ̀ nile rẹ, Mar-a-Lago, to wa n'ilu Florida, lọjọ Isẹgun.

O ni oun fẹ pada dije fun ipo aarẹ, lati gbe ogo America dìde lẹẹkan si.

"Igbe dìde America ti bẹrẹ lati asiko yii lọ."

"Nitori naa, lati asiko yii lọ titi di ọjọ idibo lọdun 2024, ni ma a ma ja fitafita lọ́nà ti ko sẹlẹ ri.

Ao ṣẹ́gun àwọn ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu Democrats to n gbiyanju lati pa orile-ede wa run gẹgẹ bi ọ̀tá ilé."

O ni ija naa kọjá ọrọ oṣelu, 'ijijagbara nla ni'.

Trump ni ìpinnu òun ni lati doola orile-ede America lo mu ki oun tun fẹ gbe igba ibo lọdun 2024.

Ṣáájú ikede yii ni wọn ti di ẹbi ijakulẹ ti ẹgbẹ́ Republican ni, ninu idibo ilaji sáà to waye.

Pupọ ninu awọn oludibo kọ awọn oludije to ṣe atilẹyin fun ariwo magomago ibo ti Trump pa lọdun 2020. Ọ̀pọ̀ àwọn to si yàn lo fidirẹmi.

Ko to o le dije fun ipo aarẹ, Trump nilo lati bori ninu idibo abẹle ẹgbẹ́ Republican.

Ọsẹ to kọja ni Trump sọ òkò ọ̀rọ̀ si gomina ipinlẹ Florida, Ron DeSantis, ti Ireti wa pe oun naa yoo dije fun ipo aarẹ lábẹ́ asia ẹgbẹ́ Republican lọdun 2024.

Bi Trump si ṣe n kede erongba rẹ, ní àwọn alatilẹhin rẹ ti n gba ipe ati imeeli fún owo dida.

Aarẹ nigba kan ri ọhun si ti ní eto ìpolongo nla silẹ.

Trump padanu sọwọ Aarẹ Joe Biden, lasiko to dije fun saa keji lọdun 2020.

Ivanka

Oríṣun àwòrán, @Ivanka

Mi o ni ṣe atilẹyin fun baba mi - Ivanka Trump

Ninu iroyin míì, ọmọbìnrin Trump, Ivanka, ti sọ pe oun ko nii ṣe atilẹyin fún erongba baba oun lati dije lọdun 2024.

Ivanka ni lootọ ni oun nifẹ baba oun, sugbọn idile oun ni oun fẹ mojuto, ki oun si daabo bo wọn lasiko yii.

O ni gbogbo atilẹyin ti oun yoo ba fun baba oun ko nii lọwọ oṣelu ninu.

Ivanka ati ọkọ rẹ, Jared Kushner, ko ipa pataki ninu isejọba akọkọ Trump. Ipo oludamọran àgbà lo fi àwọn mejeeji si.