Russia sẹ́ pé àwọn kọ́ ló ju àdó olóró sí Poland ṣùgbọ́n Zelensky ni pé Ó jù sí Ukraine lásìkò tí ìpàdé G20 ń lọ lọ́wọ́

Ukraine

Oríṣun àwòrán, Reuters

Saaju ni Zelensky to jẹ aarẹ Ukraine ti sọ pe Russia lo ju ado oloro naa si Poland ati pe igbesẹ yii fihan pe Russia ko fe ki ogun naa pari.

Zelensky sọ pe bi Russia se ju ado oloro naa si Ukraine ti fihan pe Moscow ko fe ki ogun naa pari lasiko yii.

O ni aadorun un ado oloro ni Russia ti ju bayii to ti ba ọpọlọpọ nkan jẹ.

Ki ni Biden n sọ?

Joe Biden to jẹ aarẹ ilẹ America ti sọrọ lori ado oloro to dun ni Poland pe o ṣeeṣe ko ma jẹ pe Russia lo ju u bi ọpọ ṣe n ro.

Ki ni o ti kọkọ ṣẹlẹ?

Ikọ ọmọ ogun Russia ti sọ ado oloro siluu Kyive, to jẹ olu ilu Ukraine, eyii to ba awọn ileegbe kan jẹ.

Ado oloro Russia tun dun leralera lawọn ilu mii bii Mykolaiv, Chernihiv, Zaporizhzhia, atawọn agbegbe mii.

Asiko ti awọn adari orilẹ-ede agbaye n ṣe ipade G20 lọwọ ni Indonesia, nibi ti wọn ti bu ẹnu atẹ lu ogun naa ni ibugbamu ọhun waye.

Ni Kyiv, ile mẹta ọtọtọ ni ado oloro ba, gẹgẹ bii ohun ti mayọ ilu naa, Vitali Klitschko sọ.

Awọn adari ijọba lagbaye n ṣe ipade G20 lọwọ ni Indonesia, nibi ti wọn bu ẹnu atẹ lu ogun ti Russia gbe ti Ukraine.

Iroyin ni asiko ti minisita ọrọ ilẹ okeere Russia, Sergei Lavrov kuro nibi ipade G20 naa ni awọn ado oloro naa dun leralera.

Klitschko sọ pe ọpọ ado oloro Russia lo balẹ siluu Kyiv amọ awọn adoola ẹmi ti wa ni ikalẹ lati doola awọn ti wọn ba faragba ninu ikọlu naa.

O fi kun awọn ọkọ ofurufu to n ṣọ oju afẹfẹ aa n ba iṣẹ wọn lọ.

Gomina ilu Mykolayiv, Vitaly Kimm sọ pe igba mẹta ọtọtọ ni ado oloro balẹ si ilu oun.

Niluu Chernihiv, gomina Vyacheslav Chaus ti kilọ fun awọn eeyan rẹ lati lọ wa ibi farapamọ si.

Lọsẹ to kọja ni Russia ko awọn ọmọ ogun rẹ kuro niluu Kherson, eyii to jẹ aṣeyọri fun Ukraine.

Koda, igbesẹ naa dun mọ Aarẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky ninu, to si sọ pe ogun orilẹ-ede naa ati Russia yoo wa sopin laipẹ.