Ayọ̀ rẹ à kún, Ibẹ̀tá ń bọ̀- Cubana àti Toyin Abraham fí àdúrà ránsẹ́ sí Davido àti Chioma

Oríṣun àwòrán, others
Gbajugbaja oṣerebinrin Toyin Abraham ati Chief Cubana, Ọkan lara awọn ọrẹ timotimo gbajugbaja olorin takasufe, David Adeleke, ti ọpọ mọ si Davido ti bọ si ori ayelujara lati ṣe adura fun lẹyin iku ọmọ ọkunrin, Ifeanyi Adeleke.
Bi ọṣẹ diẹ sẹyin ni iroyin gbalẹ kan pe Ifeanyichukwu tii se ọmọkunrin kan soso ti gbajumọ akọrin takansufe ọhun bi ti jade laye.
Lori opo ayelujara ni Toyin Abraham ti rọ ojo adura le Davido ati afẹsọna rẹ, Chioma lori, to si gba ladura pe ayọ wọn maa kun.
“Ọmọ ọla, Ayọ rẹ akun,inu ẹ a dun. Ọlọrun awa pẹlu iwọ ati Chioma
"Ilọpo lọ na ilọpo ni Ọlọrinma fun yin."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Bakan an ni ọrẹ timọtimọ akọrin, Cubana Chief Priest na pẹlu Toyin Abraham lati ṣe adura fun Davido, to si ni laipẹ, ibẹta yoo wọle tọ tọkọtaya ọhun.
O wa fi n da tọkọtaya loju gbogbo ikolọ wọn ni Ọba oke yoo dapada fun, ti yoo si ṣe atunṣe aye wọn pelu
"Ọlọrun yoo lọwọ si igbesẹ wa, yoo ṣe atunṣe nitori ohun la gbojule. A wa pẹlu yin, ti a si jọ bori papọ.
"Ibẹta n bọ lọna, ki Ọlọrun ran wa lọwọ"












