Arise TV yóò san owó ìtanràn lórí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ tí wọ́n gbé nípa Tinubu – NBC

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ileeṣẹ to n risi akoonu igbohunsafẹfẹ lorilẹede Naijiria, NBC ti paṣẹ pe ileeṣẹ Arise TV yoo san owo itanran miliọnu meji Naira.
Ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ iroyin naa ni pe wọn gbe iroyin ofege nipa oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All progressive Congress, APC, Bola Ahmed Tinubu.
NBC ni ileeṣẹ Arise TV Tẹ Oju ofin to de iroyin otitọ bolẹ, ni wọn ṣe gbọdọ san owo itanran naa.
Arise TV tọrọ aforiji lori iroyin ofege nipa Tinubu
Ti ẹ ko ba gbagbe Ọjọ Isinmi ni Arise TV tọrọ aforiji lori iroyin ti wọn gbe pe Ajọ to n risi eto idibo lorilẹede Naijiria, INEC n ṣe iwadii Tinubu.
Ohun ti wọn ni INEC n ṣe iwadii rẹ le lori ni ẹsun ti wọn fi kan an pe ijọba ilẹ Amẹrika gbe ẹṣẹ le ohun ini Tinubu lasiko to n jẹ ẹjọ to n niiṣe pẹlu gbigbe oogun oloro lọ si oke okun.
Amọ INEC ni opin oṣẹ ni ko si ohun to jọ iwadii bẹẹ ti awọn n ṣe.
Eyi lo mu ki ileeṣẹ iroyin Arise TV naa kọwe sita lati tọrọ aforiji nitori iroyin ofege ti wọn gbe naa.








