Ohun tí a mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ikú ìyàwó adarí òṣìṣẹ́ ní ìlú Eko, Adedoyin Raliat Ayinde

Oríṣun àwòrán, Others
Iroyin to fi ẹṣẹ mulẹ ti jade lori ohun to ṣekupa Ọmọbabinrin Adedoyin Raliat Ayinde to jẹ iyawo olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Eko, Tayo Ayinde ṣe pa ipo da.
Ọmọbabinrin Adedoyin ni iroyin gbe pe o ku ni Ọjọ Aiku, Ọjọ Kẹtala, Oṣu Kọkanla, ọdun 2022 lẹyin ti o ṣe aisan ranpẹ.
Ọmọ ọdun mẹrindinlogoji ni arabinrin naa ki o to papoda.
Ohun ti a mọ nipa iṣẹlẹ iku abilẹkọ Adedoyin Raliat Ayinde...

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo -Olu ninu atẹjade to fi lede lati ṣedaro iku arabinrin naa salaye bi o ṣe ṣẹlẹ.
Sanwo-Olu ni Ọmọbabinrin naa to wa lati idile ọba Oniru ni ilu Eko ku lẹyin to ṣe aisan ranpẹ.
Sanwo-Olu ṣapejuwe iku rẹ gẹgẹ bi eleyii to jẹ ọgbẹ ọkan fun oun , ti oun si mọ pe o dun gbogbo eniyan to mọ obinrin naa.
O ṣapejuwe arabinrin to doloogbe naa gẹgẹ bi akinkanju obinrin to ni ifẹ araalu, to si sa ipa rẹ lati ṣe aanu fun gbogbo ẹni to ba wa ni ayika rẹ.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Eko ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi obinrin to ni ifẹ ọkọ rẹ, to si ṣe atilẹyin fun ni idi iṣẹ rẹ.
Iroyin miran lori iṣẹlẹ iku arabinrin Adedoyin Ayinde...

Oríṣun àwòrán, Instagram
Awọn iroyin miran lori iṣẹlẹ naa ni arabinrin naa gbe ẹmi mi lẹyin ọjọ keji to de lati Ilẹ Gẹẹsi, United Kingdom.
Wọn ni agbegbe Magodo ni ilu Eko ni iṣẹlẹ iku rẹ ti waye.
Iroyin ọhun ni oṣu mẹta ṣẹyin ni arabinrin naa bi ọmọ keji ni Ilẹ Gẹẹsi, ti ọkọ rẹ si wa nibẹ fun igba diẹ.
Ọmọ tuntun naa to jẹ ọmọ ikeji rẹ fun Ayinde ni wọn ni o wa ni alaafia.
Ọjọ kejila, Osu yii lo de si orilẹede Naijiria lati UK to si gbẹ mi mi lẹyin ti wọn ni o jẹ irora, ti wọn si gbe lọ si ile iwosan amọ o di ero ọrun.
Ọkọ rẹ ni wọn ṣapejuwe pe o sun ẹkun kikoro, ti wọn si ti sin oku rẹ ni Ọjọ Aje ni agbegbe Ikoyi.
Ọdun 2019 ni Ọmọbabinrin naa ṣe igbeyawo pẹlu Ayinde, ti wọn si n ṣe lọkọ-laya.












