Adebayo Titus ni oun ati Akintelure Festus jọ ja to si mu ẹ̀mí Festus lọ

Keke

Oríṣun àwòrán, Others

Ori ma jẹ ki a ṣì rin ni ariow to gba ẹnu awọn ero agbegbe Oke Aro nijọba ibilẹ Guusu Akure nipinlẹ Ondo kan.

Eyi ko ṣẹyin bi ija ṣe bẹ silẹ laawrin awakọ ero kẹkẹ 'Marwa' meji ti ọkan si gab ibẹ di ero ọrun.

Awakọ kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta taa mọ si kẹkẹ Marwa kan nilu Akure, Adebayo Titus, lo ti gbẹmi mi lẹyin ede aiyede to waye laarin oun ati akẹgbẹ rẹ kan, Akintelure Festus.

Adebayo ni iroyin fi yeni pe o padanu ẹmi rẹ lakoko ti oun ati Akintelure n fa laasigbo lori ọrọ kiko iyẹpẹ ni ibudokọ wọn lati di awọn koto kan loju popo, leyi ti Adebayo kọ lati ba wọn kopa nibẹ.

Kini ọ ṣẹlẹ gangan?

Awọn oṣojumikoro to ba BBC Yoruba sọrọ wi pe Akintelure lo koro oju si Adebayo latari pe ko bawọn lọwọ ninu iṣẹ ọhun

Àkọlé fídíò, Lukman Oyebisi Ilaka: Kò yẹ kó sí túlààsí, ìjà tàbí dídáná sunlé ara ẹni nítorí ibò

Eleyi to mu ki awọn mejeeji o maa tahun si ara wọn ko too di pe wọn wọ ijakadi leyi to mu ki Adebayo o ṣubu lulẹ ti wọn si sare gbe lọ ile iwosan.

Awọn kan ninu wọn wipe Akintelure lo lu Adebayo ni alubami leyi to mu ki wọn gbe digbadigba lọ ile iwosan.

Àkọlé fídíò, Adewole Adebayo, Olùdíje sípò Aàrẹ lẹ́gbẹ́ SDP: Mo faramọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láti mójútó aàb

Kini Olọpaa sọ lori iṣẹlẹ ọhun?

Alukoro ajọ ọlọpa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami, lakoko to ba BBC Yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ naa wi pe ọjọ Satide ni iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Oke-aro ni llu Akure.

Odunlami to wi pe aarọ ọjọ Isinmi ni oloogbe naa gbẹmimi nile iwosan ti wọn gbe e lọ lẹyin iṣẹlẹ naa.

Ni ṣe ni awọn agbofinro parọwa si awọn mọlẹbi oloogbe naa lati tẹle ilana ofin ki wọn ma ṣe da rugudu silẹ lagbeegbe naa.

O wa fikun pe Akintelure lo ti wa ni ihamọ awọn agbofinro ti iwadi kikun si n lọ lori ohun to ṣokunfa ikun Adebayo gan.