Iléeṣẹ́ ọmọ ogun kéde orúkọ agbésùnmọ̀mí 19, àti ẹ̀bùn owó ₦5m fún ẹni tó bá lè ṣamọ̀nà bí ọwọ́ yóò ṣe tẹ̀ wọ́n

Oríṣun àwòrán, News Agency of Nigeria
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti kede orukọ awọn agbesumọmi mọkandilogun ti wọn n wa lori oniruru ẹsun iṣekupanmi ati igbesumọmi.
Aworan ati orukọ awọn afurasi naa wa lara atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun, Maj.-Gen. Jimmy Akpor, fi lede niluu Abuja.
Ileeṣẹ naa kede ebun owo miliọnu marun un naira lori ẹnikọọkan wọn gẹgẹ bii iye owo ti yoo san fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi ọwọ yoo ṣe tẹ wọn.
Wọn ni awọn eeyan naa lara awọn to n da omi alaafia ipinlẹ Katsina, Sokoto ati Katsina ru.
Ọgagun Jimmy Akpor sọ ninu atẹjade naa pe ki awọn araalu pe nọmba ẹrọ ibaraẹnisọrọ 09135904467 lati ta awọn lolobo ti wọn ba mọ bi ọwọ ṣe le tẹ awọn afurasi agbesumọmi naa.
Orukọ awọn afurasi naa ree;

Oríṣun àwòrán, NAN
- Sani Dangote lati abule Dumbarum ni ijọba ibilẹ Zurmi, ni ipinlẹ Zamfara
- Bello Turji Gudda lati Fakai ni Zamfara
- Leko lati Mozoj ni ijọba ibilẹ Mutazu, ni ipinlẹ Katsina
- Dogo Nahali lati abule Yar Tsamiyar ni ijọba ibilẹ Kankara ni ipinlẹ Katsina
- Halilu Sububu, lati Sububu ni ipinlẹ Zamfara
- Nagona, lati Angwan Galadima ni ijọba ibilẹ Isa, ni ipinlẹ Sokoto
- Nasanda lati abule Kwashabawa ni ijọba ibilẹ Zurmi ni Zamara
- Isiya Kwashen Garwa lati abule Kamfanin Daudawa ni ipinlẹ Katsina
- Ali Kachalla, ti apẹle rẹ n jẹ Ali Kawaje, lati abule Kuyambara ni Dansadau Maru, ni ipinlẹ Zamfara
- Abu Radde lati abule Varanda ni ijọba ibilẹ Batsari ni ipinlẹ Katsina
- Dan-Da lati abule Varanda ni ipinlẹ Katsina
- Sani Gurgu lati abule Varanda ni ipinlẹ Katsina
- Umaru Dan Nigeria, lati abule Rafi, ni Gusau
- Alhaji Ado Aliero lati abule Yankuzo ni ijọba ibilẹ Tsafe ni ipinlẹ Zamfara
- Monore lati abule Yantumaki, ni ijọba ibilẹ Dan, ni ipinlẹ Katsina
- Gwaska Dankarami lati abule Shamushele, ni ijọba ibilẹ Zuri, ni ipinlẹ Zamfara
- Baleri, lati ijọba ibilẹ Shinkafi, ni ipinlẹ Zamfara
- Mamudu Tainange lati abule Varanda ni ijọba ibilẹ Batsari, ni ipinlẹ Katsina
- Nagala lati ijọba ibilẹ Maru ni ipinlẹ Zamfara








