Ìmọ̀ àìsàn ìtọ̀ ṣúgà tí kò kún tó ló ń fa ikú àìtọ́jọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀-Obasanjo

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @atiku

Aarẹ tẹlẹri, Olusegun Ọbasanjọ ti ké gbajare pe ki onikaluku ṣọra.

O salaye pe aini ẹkọ tabi aibikita ninu iṣakoso itọ suga ti fa iku atijọ fun ọpọlọpọ awọn alaisan arun itọ suga.

Ọbasanjọ sọ eyi lọjọ Aiku ni papa iṣere MKO Abiola, Abeokuta, nipinlẹ Ogun.

Iyẹn lasiko idije ọlọresọọrẹ to waye laarin ẹgbẹ agbabọọlu All-Stars Abeokuta ati Super Eagles nigba kan ri.

Ajọ Olusegun Ọbasanjọ Foundation lọ ṣeto idije naa gẹgẹbi ayẹyẹ Ọjọ aarun Itọ suga lgbaye ti ọdun yii.

Ninu ọrọ rẹ, Ọbasanjọ sọ pe o ti to ogoji ọdun loun ti n gbẹ pẹlu aisan ito suga.

O so pe aisan naa ko ni iwosan sugbọn a le se itọju re.

Gege bi oro re, alaisan kan lẹ gbẹ to ọgọrun ọdun ti o ba tẹle awọn imọran ati ikilọ to ro ma n itọju aisan naa

Ọbasanjọ sọ pé, “Iṣoro arun itọ suga jẹ́ iṣoro imọ ati ẹkọ to peye lori aisan naa, imọ lati mọ pe ki i ṣe arun ta a le wo san, sugbọn ti aisan to gba itọju ni.

Ọbasanjọ ni gẹgẹ bi eniyan ti o ni aisan itọ suga ko gbọdọ mu suga.

Ki eni naa Ko din jijẹ eyikeyi ounjẹto n fun ni lokun ati agbara ti oloyinbo n pe ni ' Carbohydrate' ku. Ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọrẹ naa pari si ami ayo meji si ọkan fun ẹgbẹ agbabọọlu All-Stars ti Abeokuta.