Ohun tó fa rògbòdìyàn lẹ́yìn tí wọ́n yan Ọba tuntun ní Ikirun rèé

Àkọlé fídíò, Ohun tó fa rògbòdìyàn lẹ́yìn tí wọ́n yan Ọba Ikirun tuntun rèé

Ẹnu ọjọ mẹta ni iroyin gba igboro pe wahala n waye niluu Ikirun lori ọrọ Ọba Akinrun tuntun,

Eredi ree ti BBC Yoruba ṣe kan si gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lati mọ ohun to n da rogbodiyan naa silẹ, ati pe bawo ni ọrọ ọhun ṣe jẹ gan.

BBC Yoruba kan si oloye Bamidele Onifade, to jẹ Elemo Aga ilu ikirun, to si tun jẹ ọkan gboogi lara awọn afọbajẹ ilu naa.

Elemo Aga sọ pe awọn ṣe eto ọhun bo ṣe yẹ ki wọn ṣe, amọ ọkan lara awọn afọbajẹ naa ti inu rẹ ko dun si ọmọ oye ti wọn fọwọ si lo fẹ da eto naa ru.

Elemo Aga
Àkọlé àwòrán, Elemo Aga

O ni afọbajẹ meje lo wa niluu Ikirun, amọ ọkan lara awọn afọbajẹ naa, Oloye Kareem Adetoyese, to jẹ Eesa ilu Ikirun ko fọwọ si ẹni ti wọn yan, eyii ti ijọba si ti fọwọ si.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, ẹni ti ijọba fọwọ si pe ki wọn jawe oye le lori ni awọn fọwọ si, amọ Eesa ko ba wọn fọwọ si ọmọ oye naa, ohun to fa wahala ree.

Idile Gboleru ni oye kan lẹyin idile Adedeji – Ijọba ipinlẹ Osun

Nigba to n da si ọrọ naa, Adeosun Rasaq, to jẹ olubadamọran fun gomina ipinlẹ Osun lori ọrọ oye jijẹ sọ pe lootọ idile mẹta lo n jẹ Ọba niluu Ikirun.

Amọ nigba ti asiko to fun wọn lati yan Ọba, wọn ke si idile ti oye kan atawọn meji to ku, amọ idile mẹrin lo wa lori ijoko, ti wọn ti sọ fun oun pe ọkan lara awọn idile naa ti pin ara rẹ si meji.

O ni lẹyin ipade naa ni awọn ṣadede ri iwe ile ẹjọ to sọ pe awọn idile ti oye kan ko ṣetan lati jẹ oye nitori wọn pin si ara wọn si wẹwẹ, nitori naa ki ijọba lọ si inu idile mii lati lọ mu ọmọ oye tuntun.

Rasaq sọ pe ẹni ti ilu fọwọsi naa ni ijọba pada kin lẹyin, o si rọ awọn eeyan ilu naa lati maṣe da wahala kankan silẹ lori ọrọ oye Ọba ọhun.

A ti fi ṣikun ofin mu eeyan mẹwaa lori rogbodiyan ọrọ Ọba– ileeṣẹ ọlọpaa

Yemisi Opalola
Àkọlé àwòrán, Yemisi Opalola, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Osun

Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola sọ fun awọn ti fi panpẹ ofin mu awọn afurasi to da ilu ru lori ọrọ oye Ọba naa.

O ni iwadii n lọ lọwọ lati wa finrin idi koko ọrọ naa ati pe awọn n ba iṣẹ lọ ki alaafia le jọba nipinlẹ Osun.

Wayi o, gbogbo akitiyan ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba lati kan si Oloye Kareem Adetoyese, to jẹ Eesa ilu Ikirun lati gbọ tẹnu rẹ lo ja si pabo.

Ẹkunrẹrẹ iwadii BBC Yoruba wa niu fidio to wa loke yii.