Toͅkoͅ-taya àti àwoͅn 16 míràn rí èͅwòͅn he lórí èͅsùn 419 ní ìpínlẹ̀ Oyo

Aworan

Oríṣun àwòrán, EFCC

Adajoͅ agba ni ileeͅjoͅ giga nipinleͅ Oyo ti ran toͅkoͅ-taya kan loͅ si eͅwoͅn lori eͅsun pe woͅn lu awoͅn eniyan ni jibiti lori eͅroͅ ayelujara.

Adajoͅ agba, Iyabode Yerima lo ni ki Arakunrin Aladenusi Adegboyega Ayodeji ati Sadiat Omowumi Rafiu to jeͅ iyawo reͅ, ki woͅn loͅ fi eͅwoͅn jura.

Awoͅn oͅkoͅ ati iyawo naa ni woͅn ran ni eͅwoͅn peͅlu awoͅn meͅjoͅ miran fun pe woͅn jeͅbi eͅsun eͅyoͅkan.

Awoͅn miran ti woͅn ran ni eͅwoͅn ni Adekoya Ojo Faruq Kolapo, Adekanmi Boluwatife Emmanuel, Omokaro Uyiosa Berry, Ajayi Lanre Lawrence, Babalola Segun Samuel ati Bolaji Bolarinwa Toheeb.

Gbogbo awoͅn ti woͅn fi eͅsun jibiti kan naa ni woͅn ni awoͅn jeͅbi eͅsun oͅhun

Aworan

Oríṣun àwòrán, EFCC

Adajoͅ Yerima wa ran Ayodeji lati loͅ fi eͅwoͅn oͅdun kan jura, to si ni ki iyawo reͅ loͅ fi eͅwoͅn osͅu meͅfa sͅisͅeͅ ilu, nitori oun fun oͅmoͅ ni oͅyan loͅwoͅ.

Bakan naa ni Ileeͅjoͅ ran Babalola ko loͅ fi eͅwoͅn osͅu meͅfa jura nigbati awoͅn Adekoya, Adekanmi, Omokaro, Ajayi ati Bolaji naa loͅ fi eͅwoͅn osͅu mefa sͅe ara rindin.

Ileeͅjoͅ tun pasͅeͅ pe ki awoͅn ti ade eͅsun naa sͅI moͅ lori loͅ da gbogbo ohun ini awoͅn eniyan ti woͅn lu ni jibiti pada.

Ijoͅba apapoͅ si tun gbeͅseͅ le awoͅn ohun ini gbogbo ti woͅn ri gba pada loͅwoͅ woͅn.

Eͅweͅ, awoͅn miran ti woͅn tun ri eͅwoͅn he fun eͅsun jibiti lori eͅroͅ ayelujara naa ni woͅn ran ni eͅwoͅn lati osͅu meͅta si oͅdun kan.

Ileeͅjoͅ to joko si ilu Ibadan ni ipinleͅ Oyo lo pasͅeͅ beͅeͅ.

Awoͅn woͅnyii ni Owoseni Opeyemi Emmanuel, Micheal Banjo Oluwatoyin, Mustapha Temitope Abdulsodiq, Olawuyi Olanrewaju Ridwan, Edobor Lucky Uhunoma, Ilori Peter Oladayo, Basit Kolawole Ibrahim, Falade Adeyinka Moses, Abdullahi Teslim Taiwo ati Temidayo Demilade Adebowale.

Gbogbo woͅn naa ni woͅn si jeͅwoͅ pe lootoͅ ni awoͅn jeͅbi eͅsun ti woͅn fi kan woͅn.