Adewole Adebayo, Olùdíje sípò Aàrẹ lẹ́gbẹ́ SDP: Mo faramọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láti mójútó aàbò Nàìjíríà lásìkò yìí

Àkọlé fídíò, Adewole Adebayo, Olùdíje sípò Aàrẹ lẹ́gbẹ́ SDP: Mo faramọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láti mójútó aàb

Ṣé ìdìbò máà wáyé ní 2023?

Eyi ati ọpọlọpọ ibeere miran ni BBC Yoruba beere lọwọ oludije sipo aarẹ Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, ẹgbẹ́ Elesin ni Naijiria.

Omooba Adewole Adebayo sọrọ ilẹ kun.

O ni pe nitootọ ni pe Yoruba lo kan lati tukọ orilẹede yii ṣugbọn kii ṣe arugbo ti ara rẹ ko le bikoṣe ọdọ ti ara rẹ pe pẹlu.

O ni pe a ko fẹ ẹni ti a oo tun maa gbadura pe ki ara rẹ o le mọ.

Bakan naa lo menuba idi to ṣe maa yi orin ogo Naijiria pada ni kete to ba wọle gẹgẹ bii Aarẹ.

Adewole ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Kini idahun Adewole pe Tinubu lo n ṣiṣẹ fun?

Nigba ti BBC beere boya Oloye Bola Ahmed Tinubu ni Amofin Adewole Adebayo n ṣiṣẹ fun labẹlẹ, o dahun pe ọrọ ko ri bẹẹ rara.

O ṣalaye pe tootọ lo yẹ ki ẹnu Yoruba kò lori ẹni ti yoo tukọ Naijiria ṣùgbọn oun ko faramọ agbalagba ti ara rẹ ko le pupo mọ nitori ọjọ ori ni oun ṣe jade.

O tun sọrọ lori awọn oloselu to ti n tukọ Naijiria pe wọn ti di ẹja gbigbẹ ni eyi to yẹ ki awọn oludibo dibo fun oju tuntun ninu oṣẹlu

Adewole Adebayo SDP

Lori Oro Yoruba Nation:

Amofin agba Adewole Adebayo to n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu SDP sọrọ lori ominira iran Yoruba ati idi to fi yẹ ki iran Yoruba ma mu òfo lasiko to kan wọn lati tukọ Naijiria.

O ni pe iran Yoruba kò fẹ́ ẹni tó máa di gẹrẹwu ti ìgbákejì rẹ̀ a maa dari wa.

O tun mẹnuba ohun to ni fun awọn ọdọ, awọn oniṣowo ati oṣiṣẹ ati igbesẹ to maa gbe lati fopin si iṣoro eto aabo Naijiria.

Adewole Adebayo SDP

Oríṣun àwòrán, @Adewole