Bí àwọn agbébọn ṣe pa Ọba, àwọn mẹ́ta míràn ní Imo rèé - Ọlọ́pàá

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn agbebọn ni ipinlẹ Imo ti ba ọba agbegbe Obudi-Agwa ni ijọba ibilẹ Oguta ni ipinlẹ Imo.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Imo, Michael Abattam ni awọn ẹgbẹ to n pe fun ominira agbegbe Biafra, IPOB lo ṣe iṣẹ ibi naa.

Abattam ni ikọ Ipob ati Eastern security network (ESN) lo wa ni idi ikọlu naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni eniyan mẹrin ni wọn pa ninu iṣẹlẹ naa to fi mọ Eze Ignatius Asor.

To si ni wọn gbe ibọn wa ti wọn si yinbọn pa Eze ato awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ meji.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ...

Ọjọ Aje ni iroyin iku Eze naa tan kalẹ lori ẹrọ ayelujara, ti ko si si ẹni to mọ bi Ipob sẹ ṣọsẹ naa.

Amọ ohun ti ọlọpaa sọ ni pe awọn agbebọn yabi aafin lasiko ti wọn n ṣepade lọwọ ti wọn si da ibọn bo lẹ.

Iwadii fihan pe ọkọ mẹrin ni wọn gbe wọ aafin poẹlu kẹkẹ kan ati obinrin kan.

Wọn ni niṣe ni awọnagbegbọn naa da bi ọgbọn bi ẹni pe wọn nilo iranwọ.

‘’Ọba ti ko mọ pe iṣẹ ibi ni wọn wa ṣe gba ki wọn wọ aafin, ki wọn si joko lati sọrọ.’’

‘’Bi o sẹ bi wọn lere pe ki lo ṣẹlẹ bayii ni wọn da ibọn bo Ọba ati awọn ẹṣọ rẹ meji.’’

Lasiko ti wọn n salọ ni wọn tun pa fifilantẹ kan ti wọn ba ni ọna. Eyi lo fi jẹ ẹni mẹrin ti wọn pa. Ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ti gbe oku awọn ti wọn pa naa lọ si mọsuari.