Peter Obi fi ohùn ránṣẹ́ padà sí Soludo lẹ́yìn tó ní Obi yóò fìdí rẹmi nínú ìbò Ààrẹ ọdún 2023

Peter Obi/Charles Soludo

Oríṣun àwòrán, Peter Obi/Charles Soludo

Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi ti sọ pe ariwo ẹnu ẹnu lasan ni Charles Soludo n pa pe oun ko ni de ipo Aarẹ Naijiria lọdun to n bọ

Agbẹnusọ ikọ ipolongo ibo Peter Obi, Ndi Kato lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Twitter rẹ.

Kato ni afujusun Peter Obi ati ẹgbẹ oṣelu Labour ni bi gbogbo nnkan yoo ṣe dẹrun fun awọn ọmọ Naijiria, kii ṣe ohun ti ẹnikẹni ni lero nipa bi esi idibo ọdun 2023 yoo ṣe ri.

Ọrọ naa lo jade ni esi si atẹjade ti Charles Soludo kọ ṣaaju pe eremọde lasan ni Peter Obi n ṣe pẹlu bo ṣe n dije du ipo Aarẹ Naijiria, nitori ko ni jaweolubori ninu eto idibo naa.

Ki ni esi Peter Obi si ọrọ Soludo?

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ninu atẹjade naa ni Kato ti sọ pe ṣe ni Soludo n fẹ ki awọn eeyan maa sọrọ nipa oun nitori ogo atijọ lo n lo.

O ni “O jọ bii pe Soludo n fẹ ipologo ara rẹ lasiko eto idibo yii pẹlu ọrọ to sọ ni.”

O tẹsiwaju pe Obi ti ni awọn alakalẹ bo ṣe fẹ ṣe ipolongo ibo rẹ, eredi ree to fi n ṣe ipade pẹlu awọn alẹnulọrọ laarin ilu ṣaaju eto idibo naa.

O fikun pe bi ọrọ apanilẹrin lasan ni atẹjde Soludo ri, ko si tu iru kankan lara awọn.

Kato pari ọrọ rẹ pe bi ayipada yoo ṣe de ba igbe aye awọn ọmọ Naijiria ni afojusun awọn, kii ṣe erongba Soludo.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Wó àwọn òkò ọ̀rọ̀ tí Soludo sọ̀ sí Peter Obi

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gomina Ipinlẹ Anambra, Chukwuma Soludo ti tako erongba oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi lati di aarẹ orilẹede Naijiria.

Gomina tẹlẹ fun banki apapọ lorilẹede Naijiria ninu atẹjade kan ni Obi fun ara rẹ mọ pe oun ko ni wọle gẹgẹ bii aarẹ sugbọn o fẹ fi ọgbọ́n sì.

"Ẹ jẹ ko ye wa: Peter Obi ko ni ibi kankan lati lọ, o mọ pe oun ko le wọle, ko si ni wọle. Ó mọ ohun to ṣe, awa naa mọ ohun to ṣe, o si mọ pe a mọ.

"Ohun to ṣe yìí jẹ idi kan pataki ti ko le fi pada sinu ẹgbẹ oṣelu APGA. Otitọ ọrọ nipe awọn meji nìkan dupo aarẹ yii, tí awọn yooku kan ṣe ere sinima lasan ni."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Soludo tẹsiwaju pe oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party ko kojuosuwon lati di aarẹ orilẹede Naijiria.

"Ohun iyalẹnu lo jẹ fun mi nigba ti mo gbo pe Peter Obi darapọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, ẹgbẹ oṣelu tí ko ni ẹsẹ nílẹ rara lati fi koju ẹgbẹ oṣelu PDP, to sapejuwe gẹgẹ bii olugbala Orilẹede Naijiria ni bi ọsẹ diẹ sẹyin ko to darapọ mọ wọn.

"Obi yii ṣe ìbúra fun Ojukwu pe oun yoo fi oṣelu silẹ kete ti oun ba ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APGA.

"Ẹgbẹ Oṣelu APGA ni ẹgbẹ oṣelu kẹta to tobi lorilẹede Naijiria, ohun ìyalẹnu ni bíi awọn kan ṣe n pariwo kiri pe ki oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APGA juwọ silẹ fun Peter Obi.

"Kete ti Obi gbọ pe oun ko ni ni anfani lati gba tikẹẹti lati dupo gẹgẹ bii aarẹ tabi igbakeji aarẹ ni o morile ẹgbẹ oṣelu Labour Party.

Ẹgbẹ oṣelu tí gbogbo wa mọ pe awọn ma gba awọn oloṣelu to padanu eto ìdibo abele.

Gomina ipinlẹ Anambra wa parí pe oun pe adura oun ni kí Peter Obi borí ninu eto ìdibo aarẹ lọdun 2023.