A ó ṣe ìfẹ̀họ́núhàn káàkiri Naijiria bẹ̀rẹ̀ láti óní lórí ààbọ̀ owó oṣù tí ìjọba san fún wa– ASUU

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ olukọ fasiti ni Naijiria, ASUU ti kede pe awọn yoo gunle ifẹhọnuhan ọlọjọ kaakiri orilẹede Niajiria.
ASUU awọn yoo ṣe iwọde yii lati tako igbese ijọba lori pe ẹni ti ko ba ṣiṣẹ ko ni gba owo oṣu.
Ifẹhọnuhan naa ni yoo waye ni ipinlẹ de ipinlẹ kaakiri awọn fasiti ijọba lorilẹede Naijiria ti wọn si fi idi rẹ mulẹ fun awọn oniroyin.
‘’A n fẹhọnu han lori igbeṣẹ ijọba, ko ba wa lara mu ki wọn ma san owo osu aabọ fun wa’’
‘’Awọn ẹka kọọkan ni yoo mu ọjọ ti wọn fẹ ṣee iwọde wọn.’’
Awa ki n ṣe oniṣe ti ko fẹṣẹmulẹ, ijọba ko lee maa ṣe wa baṣubaṣu.’’
Ọjọ Iṣegun, ọla ni UNILAG yoo ṣe ifẹhọnuhan rẹ...

Oríṣun àwòrán, Others
Ninu atẹjade ti Alaga ASUU ni fasiti Eko, UNILAG, Dr Dele Ashir fi ṣọwọ si awọn ẹgbẹ ni ọjọ karundinlogun ni awọn yoo sẹwọde ti wọn.
Ninu lẹta naa naa ni wọn ti fi lede pe pe gbadeke Julius Berger Auditorium ni yoo ti waye.
Amo ninu esi ijọba apapọ ni wọn ti sọ wi pe aṣẹ ijọba ni pe ẹni ti ko ba ti ṣiṣẹ, ko ni gba owo oṣu.
Oṣu mẹjọ ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU fi gunle iyanṣelodi lori ẹsun pe ijọba ko san owo ajẹmọnuwọn , to fi mọ atunṣe awọn fasiti to ti dẹnukọlẹ lorilẹede Naijiria.












