Nkan mẹ́jọ tí o le ṣe láti dáàbò bo ara rẹ tí o bá ń rìn lójú pópó

Àwọn ọkọ loju popo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fifi ẹsẹ rin lójú pópó, paapaa ni àwọn ojupopo nla ni ewu pupọ.

Idi ni pe orisirisi ọkọ bii ayọkẹlẹ, bọọsi, ọkọ akẹru, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gbogbo awakọ sì kọ lo ma n kiyesara. Ẹlòmíràn le ti mu ọtí yo, awakọ̀ mii le ma sọ̀rọ̀ lori foonu, tabi ko ma tìẹ wo ibi to n lọ.

Àwọn ihuwasi yii si má n fi àwọn to n fi ẹsẹ rin lojupopo sinu ewu nla.

Ọjọru ni iroyin jade pe awakọ kan pa ọgagun kan ninu ọgbà àwọn ologun n'ilu Eko.

Iroyin sọ pe awakọ naa to jẹ ọmọ ogun, Abayomi Ebun, fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ pa Ọgagun A. O. James ninu baraaki ológun, NAFRC.

Ọgagun James n pada sile rẹ ninu ọgbà naa ni nkan bi aago mẹwaa aabọ alẹ ni ijamba naa waye.

Iku Ọgagun yii jẹ ẹyọkan lara iku to n pa àwọn to n fi ẹsẹ rin lojupopo.

Lati wa a daabo bo ara rẹ ti o ba n fi ẹsẹ rìn, awọn ilana kan re e.

Gẹ́gẹ́ bi Àjọ ẹ̀ṣọ̀ ojupopo ni Naijiria, Federal Road Safety Corps, FRSC, ṣe sọ, rinrin ni ojupopo gba ọpọlọpọ ikiyesara.

Ninu eto ilani lọyẹ to fi si ori ayelujara Facebook rẹ, àwọn ilana yìí ni FRSC là kalẹ fun àwọn to n fi ẹsẹ rìn lojupopo:

Rin ni ori pepele to wa lẹgbẹ ona tabi ni eti ojupopo ti ko ba si pepele kankan.

  • Apa ọtun ojupopo ni ki o ti ma a rin, ki o le ma ri àwọn ọkọ to n bọ lọ́nà ọdọ rẹ
  • O ni lati sọra gidi, ki o si kiyesara to ba n rin ni ibi ti oju rẹ ko ti ri ọna jinjin loju popo
  • Aarin gbùngbùn pepele ẹgbẹ́ ojupopo ni ki o ti ma a rin. Ìdí ni pe ẹnikan le deede ṣi ilẹkun ọkọ, o si le gba ọ ṣubú
  • Ti ẹnikan ba pe ọ lati òdì-kejì ojupopo, wo lilọ-bibọ ọkọ daadaa ki o to sọdá lati ki wọn.

Àwọn ilana míì to tun le lo ni:

  • Fi oju, eti ati ọkàn si nkan to n lọ ní ayika rẹ lojupopo. Eyi nii ṣe paapaa fun awọn to ma n fi nkan sinu etí lati gbọ orin tabi awọn to ma n wọ igo dudu si oju wọn.
  • Fífi nkan sinu eti ko nii jẹ ki o gbọ ìró ọkọ, wíwọ igo dudu naa si le ma jẹ́ ki o rina daadaa.
  • Ma ni i lọkan pe awakọ yoo duro fún ọ lati kọjá. O le bẹ awakọ ko duro fun ọ, tabi ki o duro ki gbogbo ọkọ lọ tan ki o tó gbiyanju lati sọdá.
  • Nibi ti afara ba wa, ma ṣe jẹ ki oroju tabi ọlẹ mu ọ sọdá lójú popona ńlá. Gun afara naa re kọjá si ibi ti o n lọ.