Ta ni Họ́nọ́rébù tó jáde láyé ni Jos lẹ́yìn ìpolongo APC?

Honorebu Olayiwola Olawale

Oríṣun àwòrán, Lagos state assembly

Ta ni Họnọrebu Olayiwola Olawale, aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko tó jáde láyé?

Aṣofin kan ni ipinlẹ Eko, Họnọrebu Sobur Ọlayiwọla Ọlawale ti jade laye.

Họnọrebu Ọlawale ti ọpọ mọ si Omititi, n ṣoju fun ẹkun Mushi keji ku ni ilu Jos lọjọ Iṣẹgun.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko fi sita fi idi iku rẹ mulẹ

Iroyin sọ pe o ṣubululẹ ni papakọ ofurufu ilu Jos ni ipinlẹ Plateau nigba to n pada bọ lati ibi eto iṣide ipolongo fun oludije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu naa fun idibo aarẹ to n bọ lọdun 2023.

Ni ọjọ Iṣẹgun ni eto naa waye ni papa iṣire Rwang Pam nilu Jos nibi ti aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari, oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Ahmed Bọla Tinubu atawọn eekan ẹgbẹ oṣelu naa peju sii.

Lati ọdun 2015 ni o ti n ṣoju fun ẹkun Mushin nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko.

Họnọrebu Ọlawale yii ni alaga igbimọ tẹẹkoto lori amojuto ijọba ibilẹ ati ibagbepọ ilu.

Ta ni Họnọrebu Ọlayiwọla Ọlawale?

Ni ọjọ kejila oṣu kẹta, ọdun 1964 ni wọn bi Họnọrebu Ọlayiwọla Ọlawale, ilu Abẹokuta lo si gbe dagba.

Ilu Abẹokuta kan naa lo ti ka iwe bẹrẹ lati alakọbẹrẹ ati girama rẹ.

O kẹkọ gboye ijinlẹ ninu imọ akoso okoowo ni fasiti ilu Eko, UNILAG ki o to wa lọgba imọ kun imọ pẹlu oye keji ni fasiti ninu imọ akoso ilu ni fasiti ipinlẹ Elẹ Eko, LASU.

O ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọni, ki o to darapọ mọ ẹka iṣẹ aladani ti o si tun da ileeṣẹ ara rẹ silẹ lọdun 1996.

Lati igba ti saa oṣelu kẹrin ti bẹrẹ lorilẹede Naijiria lo ti n kopa ti oun pẹlu si dara pọ m oṣelu.