Èèyàn tó wà láyé pé Bílíọ́nù mẹ́jọ, mọ̀ nípa àwọn tó mú u kó pé bẹ́ẹ̀

Sadia Sultana Oishee

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ni iye eeyan to wa ni agbaye pé biliọnu mẹjọ, lẹyin ọdún mọkanla to pe biliọnu meje.

Ajọ United Nations to fi ikede naa sita sọ pe bi eeyan ṣe n pọ si laye ti n dinku bayii ju bo ṣe pọ ni ọgọrun ọdun to kọja.

Wọn ni yoo gbà to ọdun mẹẹdogun si asiko yii ko to o pe biliọnu mẹsan-an.

Ọdun 2080 si ni eeyan to wa laye yoo pe biliọnu mẹwaa.

Ajọ UN sọ pe o nira pupọ lati le sọ iye eeyan to wa laye ni pàtó, sugbọn yoo ni iyanju laarin ọdún kan si meji.

Ni awọn ọdun to ti kọja, ajọ UN yan àwọn ọmọ to wa ni ipo biliọnu marun-un, mẹ́fà ati meje.

Ọmọ to mu ki eeyan to wa laye pe biliọnu marun-un

Wọn bi Matej Gaspar ni ọdun 1987, nílùú Zagreb, lorile-ede Croatia.

Lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn bi, awọn oloṣelu ati ayaworan yi ibi ti wọn bi sí ká, lati le ri i.

Bi àwọn eeyan pataki ṣe péjọ lati ri Matej, ko ṣẹyin bi wọn ṣe kede pe ìbí rẹ lo mu iye ọmọ to ti wọ aye pe biliọnu marun-un.

Ọga agba ajọ UN lasiko naa, Alex Marshall iwoye ti wọn ni ṣáájú ni pe ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 1987, ni ẹni to wa ni ipo biliọnu marun-un yoo wọ inú ayé.

Nitori naa ni wọn ṣe yàn-án.

Àwọn oṣiṣẹ ajọ United Nations lasiko naa beere idi to fi jẹ pe ọmọ kan ṣoṣo ni wọn yan, Ọgbẹni Marshall ṣàlàyé pe awọn kan nilo lati fi ọmọ tuntun kan sọ rí onka naa ni.

Lẹyin ọdun marundinlogoji, akọsilẹ nipa Matej lori Facebook fihan pe o ṣi n gbe ni ilu Zagreb, o ti bimọ, o si ti di onimọ ẹrọ. Sugbọn o kọ lati ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC.

Biliọnu mẹta eeyan lo ti wọ inu ayé lati ọdun 1987, sugbọn asọtẹlẹ fihan pe biliọnu meji pere ni yoo wọ inú aye laarin ọdun marundinlogoji to n bọ̀.

Eyi fihan pe adinku n ba bi ènìyàn ṣe n pọ̀ si ninu ayé.

Ọmọ to wa ni ipo biliọnu kẹfà

Adnan Mevic

Adnan Mevic, ọmọ ti wọn bi ti iye eeyan to wa laye fi pe biliọnu mẹfa, n gbe ni Bosnia-Herzegovina. Ọdun 1999 si ni wọn bíi.

Orile-ede Bosnia wa lara awọn ti iye onka wọn kere julọ, asọtẹlẹ si fihan pe ìlàjì iye àwọn ènìyàn orile-ede naa lọwọlọwọ ni yóò kù, tii yoo bà fi to aadọta ọdún.

Bi awọn eeyan orile-ede Bosnia ko ṣe ma a bimọ pupọ, ati bi wọn ṣe lọ n gbe ni àwọn orile-ede míì, lo fa ìṣòro yii fun wọn.

Adnan n gbe n'ilu Sarajevo pẹlu iya rẹ, Fatima, àmọ́ ko ri isẹ ṣe botilẹ jẹ pe o ni iwe ẹri imọ ijinlẹ kejì 'Masters', ninu eto ọrọ ajé.

Ọmọ to wa ni ipo biliọnu keje

Sadia Sultana

Sadia Sultana Oishee ni wọn yan si ipo biliọnu keje.

Wọn bi Oishee lọdun 2011, oun si lo kere ju ninu ẹbi rẹ.

Ọganjọ oru ni wọn bi, ti àwọn eeyan ati awọn ayaworan si tun pejọ lati ki kaabọ, bi wọn ṣe ṣe fun Matej.

Oishee sọ pe iṣẹ dokita ni oun fẹ ṣe, baba rẹ si ni oun yoo gbiyanju lati mu ki àlá rẹ ṣẹ.

Kini eyi nii ṣe pẹlu ilẹ̀ Africa?

Gẹgẹ bi ajọ United Nations ṣe sọ, orile-ede mẹjọ ni ìlàjì àwọn ènìyàn ti yoo kún awọn to wa laye tẹlẹ, ti yoo ba fi di ọdún 2050, yoo ti wá.

Àwọn orile-ede naa ni Naijiria, Pakistan, Ethiopia, Congo, Egypt, Philippines ati Tanzania.

Asọtẹlẹ ajọ UN tun sọ pe Naijiria ati awọn orile-ede míì to wa ni ilẹ̀ olooru Africa, to fi mọ awọn kan ni Latin America ati Caribbean, yoo ni àwọn ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdún mẹẹdọgbọn si mẹrinlelọgọta.

Wọn ni eyi yoo mu ki ọ̀rọ̀ aje àwọn orile-ede naa dagba soke.