Kwara Kidnap: N20 mílíọ̀nù ni wọ́n kọ́kọ́ bèèrè fún, mo ta mọ́tò, mo fi ìwé ilé lọ yáwó- Lukman Aliyu

Àkọlé fídíò, Kwara Kidnap: N20 mílíọ̀nù ni wan kọ́kọ́ bèèrè fún, mo ta mọ́tò, mo fi ìwé ilé lọ yáwó- Lu

Wọ́n ko foonu wa ati ti ẹni tó wa 'charge' tiẹ naa, wọn ko 5 alive, owo ati buredi pẹlu ọmọ meji lẹyin ti wọn ti fi ibọn ba ile wa jẹ- Lukman Aliyu

Oju awọn ọmọ Naijiri an ri to lasiko yii lọwọ awọn ajinigbe.

BBC wa ẹbi Lukman Aliyu kan ni agbegbe Alagbado ni ilu Ilorin ni ipinlẹ Kwara.

O ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ ninu ile rẹ laarin oru ni Ilorin, bi wọn ṣe da ibọn bolẹ nibẹ ti wọn si ba gbogbo ile naa jẹ ki won to ri ilẹkun ja wọle.

O ni igba kẹta ree ti ajinigbe maa ṣọṣẹ nla ni adugbo naa ti wọn ti pa ẹni kan ti wọn si ti gab ọpọlọpọ miliọnu bayii lọwọ awọn ara adugbo.

Ajinigbe ba ile Lukman jẹ

Kini O tun ṣẹlẹ?

Aliyu sọ pe ko si aladugbo to le koju ibọn ti wọn gbe wa ni eyi ti awọn gba kadara si.

O ni pe gbogbo ara adugbo lo ti sa kuro tan nigba ti ko si eto aabo.

O ni pe awọn ajinigbe sọ pe ki awọn lọ wa ẹni to gbọ ede Hausa wa ko le ba wọn duna dura ki wọn to pada gba miliọnu marun un lọwọ wọn.

Bẹ́ẹ̀, Agbẹnusọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara sọ fun BBC pe oun ko gbọ si iṣẹlẹ naa rara