Ǹ kò wó 'Social media' mọ nítorí èébú tí wọ́n ń bù mí tí pọ̀jù- Tinubu

Oríṣun àwòrán, others
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti sọ idi ti oun ko fi n wo ẹrọ ayelujara ‘Social Media’ mọ, nitori pe awọn eeyan ma n bu oun.
Tinubu ṣo eleyii lori fidio kan to n ja ranyin lori ero ayelujara.
Ohun ti Tinubu sọ ninu fidio naa ni pe ọpọ igba awọn ọmọ oun tabi awọn osisẹ lo n ba oun ka awọn esi ti awọn eeyan ba fi ransẹ si oun lori ayelujara nitori pe pupọ ninu wọn ni eebu.
“N ko de idi Social Media mọ rara, wọn sọ awọn oko ọrọ nipa mi, ti n ba ti ẹ wa ni mo ka, ma ni ẹjẹ riru, maa binu lọpọpọ.
''BP'' mi ma n ru soke pẹlu bi wọn ṣe n bu mi lori ayelujara - Tinubu
“Ti n ba fẹ ka nkankan, awọn ọmọ mi tabi awọn osisẹ mii lo ma ni eleyii sọ bayii, tọun sọ eleyii. To ba ti sumi, ma ni ki wọn da duro, ẹ gbagbe rẹ.”
''Nise ni ẹjẹ mi ma n ru si oke ti wọn ba ti bu mi lori ẹrọ ayelujara, nitori naa maa ni ki wọn ma tilẹ sọ fun mi nkan ti ẹni bayii sọ.''
Ẹgbẹ oselu APC kede pe Oloye Asiwaju Bola Ahmed Tinubu gẹgẹ bii ẹni to gbegba oroke ninu ibo abẹnu to se fun awọn oludije to fẹ du ipo aarẹ orilede yii.
Tinubu bori eto idibo naa, to si fi idi awọn oludije yoku janlẹ ninu ibo ọhun.
Ọ̀rẹ́ làwọn olóṣèlú, ohun tí wọn yóò jẹ ni wọ́n ń wá, ẹ má pa ara yín nítorí wọn– Matthew Kukah

Oríṣun àwòrán, Tinubu
Biṣọọbu ijọ Aduga ipinlẹ Sokoto, Mathew Kukah ti ke si awọn ololufẹ awọn oloṣelu lati ma pa ara wọn nitori oloṣelu kankan.
Kukah lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Channels lẹyin wakati diẹ ti aworan kan jade nibi ti Bola Tinubu ati Atiku Abubakar ti n yọ mọ ara wọn ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe to wa niluu Abuja.
O ni ọrẹ ni gbogbo awọn oloṣelu, ohun ti wọn yoo si jẹ ni wọn n wa, ko si yẹ ki awọn ololufẹ wọn maa ba ara wọn ja lori ọrọ oṣelu.

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters
Alufa naa ni o yẹ ki awọn to n tẹle awọn oloṣelu kẹkọọ lara Tinubu ati Atiku ti wọn di mọ ara wọn lai si ikunsinu kankan lasiko ti wọn pade ni papakọ ofurufu.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, o n tumọ si pe awọn ololufẹ awọn oloṣelu naa gbọdọ gba alaafia laaye ninu eto oṣelu ti wọn n ṣe.
O ni “Gbogbo aye wọn lawọn oloṣelu yii n fi n wa bi wọn yoo ṣe jẹ lara Naijiria, ti wọn yoo si pin laarin ara wọn.”
“Awọn eeyan to n tẹle wọn si gbọdọ mọ pe awọn oloṣelu yii mọ ara wọn.”
Lẹyin naa lo rọ awọn araalu lati fi ọgbọn ṣe oṣelu ti wọn n ṣe lai si ẹtanu kankan tabi ipalara fun ọmọlakeji wọn.
Ti ẹ ko ba gbage, inu oṣu Kẹwaa ọdun yii lawọn janduku kan kọlu ikọ ipolongo Atiku Abubakar niluu Kaduna, ti wọn si da ipolongo ti wọn lọ ṣe nibẹ ru.
Bakan naa lọsẹ to kọja, iroyin ni awọn janduku mii kọlu awọn eeyan Atiku nipinlẹ Bornu.
Yatọ eyii, oniruru iroyin lo ti n jade nipa bi awọn janduku ṣe n sọ ina si ọọfisi ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, INEC.












