Púpọ̀ àwọn tó ń bu mi pé mo yan Shettima gẹ́gẹ́ bíi igbákejì mi ló nífẹ̀ẹ́ sí ipò náà – Tinubu

Oríṣun àwòrán, @officialABAT
Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni pupọ lara awọn to bu ẹnu atẹ lu bi oun ṣe kede Kashim Shettima gẹgẹ bii igbakeji oun ni wọn nifẹ si ipo ọhun.
Tinubu salaye pe pupọ lara awọn ni wọn jẹ ọrẹ timọtimọ ti oun kuna lati mu gẹgẹ bii igbakeji Aarẹ saaju eto ìdibo ọdun 2023.
O sọ eleyii nigba to n ṣe ipade pọ pẹlu awọn adari ọmọlẹyin kristi, CAN, eyii ti Bisọọbu Agba Daniel Ukoh le waju wọn.
O ni "Awọn eeyan kọminu lori igbesẹ mi. Wọn binu nitori ọrẹ ni wọn jẹ simi, wọn nifẹ lati di igbakeji mi sugbọn mo kọ lati ba wọn ṣe pọ."
"Iroyin ofege ni pe mo n gbinyanu lati kọ iyan awọn ọmọ kristẹni kere. Emi ko ni erongba to jẹ mọ yẹn rara."

Oríṣun àwòrán, @officialABAT
"Se emi ti mo kuna lati koyan ẹsin Kristẹni kere ninu mọlẹbi mii ni maa ni mo fẹ koyan Kristẹni kere lorilẹede Naijiria lapapọ?"
"Ti n ba gbe apoti ibo Aarẹ ninu mọlẹbi mi bayii, mi o le wọle nitori gbogbo wọn ni wọn ni Kristẹni.
"Fun idi eyi, n ko le sọ orilẹede Naijiria di orilẹede Musulumi nikan."
Idi ti mo fi yan Shettima
Oludije ẹgbẹ oṣelu APC ọhun tẹsiwaju pe o rọnu fun oun lati mu igbakeji lati ninu ẹsin Kristẹni ṣugbọn oun ko ronu gba ọna ẹsin rara.
O ni, "Idi ti mo fi yan Shettima ki n ṣe nitori pe a jọ jẹ ọmọ ẹlẹsin kan naa, ṣugbọn nitori pe o ni oye ati ọgbọn ti yoo ṣe iranlọwọ fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria.
"Mo yan Shettima nitori pe o jẹ ẹnikan ti yoo ṣe iranlọwọ fun mi lati ṣe ijọba, kii n ṣe lati ṣe ẹsin."
O wa rọ awọn ọmọlẹyin Kristi lati ṣe atilẹyin fun oun nitori pe ẹni ti oun yan gẹgẹ bii igbakeji ni oun ni igbagbọ pe yoo fọwọsowọpọ pẹlu oun fun ilọsiwaju Naijiria.












