Bàbá olówó kan bẹ̀rẹ̀ ìkówójọ $25b fún àtúnṣe orílẹ̀èdè Ukraine lẹ́yìn ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Baba olowo onisowo kan, Andrew Forest ti setan lati bẹrẹ ikowojọ oni biliọnu mẹdọgbọn owo dọla fun atunṣe orilẹede Ukraine lẹyin ogun to n waye nibẹ.
Forrest ati iyawo rẹ ti ṣe afikun owo naaz pẹlu owo ti iye rẹ milọnu lọna ọgọrun un marun un owo dọla, ti awọn to ṣe agbatẹru ikowojọ naa si ni owo ọhun ko ni pẹ di ọgọrun un bilọnu owo dọla.
Ajọ Ukraine Green Growth ti n gbaradi lati fi owo naa pese awọn ọhun to yẹ lẹyin ikọlu Russia silẹ naa.
Aarẹ Volodymyr Zelenskyy ti wa gba igbesẹ naa wọle.
Zelensky ni “A o lo anfani lati mu atunṣe ba awọn dukia ti Russia bajẹ, ti a a si parọ wọn pẹlu ti igbalode.”
Owo naa ti wa lọwọ Larry Fink, to jẹ ọga agba fun ileeṣẹ BlackRock, ti igbagbọ si wa pe afikun yoo de si owo naa lati ọdọ awọn onisowo yoku.
Forrest ni lati ninu oṣu kẹta ni igbesẹ kiko owo yii jọ ti bẹrẹ, ti oun si ti fi ọrọ ranṣẹ si ọpọlọpọ awọn olori bii aarẹ Joe Biden, Olootu agba tẹlẹ nilẹ UK, Boris Johnson ati aarẹ fun awọn orilẹede Euro Ursula von der Leyen, sọrọ lori igbesẹ ọhun.
Forrest sọ fun BBC pe "Aarẹ Zelensky ri igbesẹ yii gẹgẹ anfani lati mu atunṣe gbogbo ikolọ Ukraine, ki tuntun si wọle.
"Atunṣe yoo olu ilu orilẹede Ukraine kete ti awọn ọmọ ologun Russia ba ti kuro ni awọn ilu yooku."












