Sunday Igboho sọ̀rọ̀ nílú Ibadan, Ó ní k'ọ́mọ Yorùbá lọ fọkàn balẹ̀, òun ń bọ̀ nílé láìpẹ́

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, other

Aṣiwaju ẹgbẹ to n ja fun ijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Igboho tun ti fi da awọn ololufẹ rẹ loju pe ko si ohunkohun to yẹ ijangbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba lẹsẹ silẹ o.

Sunday Igboho ni bi o ti wu ki ipenija o pọ to fun oun, oun ko lee ja ijangbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba ju silẹ rara ni.

Ninu ọrọ to ba awọn to pejọ sibi ayẹyẹ eto ọjọ ibi lẹyin iku fun Ajayi Crowther nilu Ibadan ni Igboho ti sọ eyi.

Igboho ni ipadabọ oun si orilẹede Naijiria ko ni pẹ mọ nitori pe ninu iwoye oun asiko to fun itusilẹ ẹya Yoruba.

Ajijagbara ẹya Yoruba naa sọrọ lori ẹrọ ayelujara Zoom pe laipẹ gbogbo wahala ijinigbe, igbenipa ati ipenija ọrọ abo gbogbo yoo dopin.

Bẹẹ lo fi da wọn loju pe gbogbo awọn kọlọrọnsi to n dun mọhuru nilẹ Yoruba yoo dopin ti ominira ilẹ Yoruba yoo si di oun fun idagbasoke ẹya naa.

“Ọrọ mi si gbogbo ọmọ Yoruba jakejado agbaye, ti wọn n poungbẹ fun idaduro orilẹede tiwọn, ni pe ki wọn maṣe sọ ireti nu. O da mi loju bi ada pe a ti wa loju ọna ominira. Ijijagbara wa ti fidi mulẹ nitori akoko rẹ gan an ti to. Mo n bọ nilẹ Yoruba laipẹ.”