Super Flamingoes Nàìjíríà yóò kojú Amẹ́ríkà ní ìpele ‘Quarter finals’ ìdíje ‘FIFA U-17 World Cup’

Awọn agbaboolu Super Flamingoes

Oríṣun àwòrán, FIFA Women's World Cup

    • Author, Olubayode Alebiosu
    • Role, Broadcast Journalist
    • Reporting from, Lagos

Lẹyin to bori ikọ Chile ni ifẹsẹwọnsẹ to kẹyin ni ipin B nibi idije ife ẹyẹ agbaye fawọn ọjẹ wẹwẹ tọjọ ori wọn ko ju mẹtadinlogun lọ lorilẹede India, ikọ agbabọlu Flamingoes ti Naijiria yoo koju orilẹede Amẹrika ni ipele Quarter fina lọjọ Ẹti.

Ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye ni papa iṣire ilu Mumbai lorilẹede India, agogo mejila Naiijiria si ni yoo waye.

Ikọ agbabọọlu Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Fifa u-17 world cup

Fun orilẹede Amẹrika ni tirẹ, igba akọkọ niyi lati ọdun 2008 ti awọn ikọ agbabọọlu obinrin wọn ti ọjọ ori wọn ko ju mẹtadinlogun lọ yoo maa kọja ipele akọkọ ni idije ife ẹyẹ agbaye.

Ikọ agbabọọlu Obinrin Amẹrika na Morocco ni goolu mẹrin si odo lọjọ Aje.

Amẹrika lo wa loke tente ipin wọn pẹlu ami meje pẹlu goolu mẹtala.

Igba mẹrin ọtọọtọ ni Naijiria ti kogoja fun ipele Quarter finals lati igba ti idije yii ti bẹrẹ.