Diego Jota, Alexander Isak kò ní kópa ní ìdíje ife ẹ̀yẹ ‘World Cup’ nítorí ẹsẹ tí wọ́n fi ṣèṣe

Alexander Isak

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Olubayode Alebiosu
    • Role, Broadcast Journalist
    • Reporting from, Lagos

Atamatase agbabọọlu Newcastle, Alexander Isak lee maa gba bọọlu mọ titi di ẹyin idije ife ẹyẹ agbaye loṣu kejila.

Gẹgẹbi ọrọ ti akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Newcastle, Eddie Howe sọ, Isak fi itan rẹ ṣeṣe ni eyi ni yoo si mu ki o maa lee tayo lori papa fun igba diẹ.

Igba mẹta pere ni Isak tii gba bọọlu fun Newcastle lati igba ti wọn ti ra a ni ọgọta miliọnu pọun lati Real Sociedad loṣu kẹjọ.

Bakan naa ni Diego Jota agbabọọlu Liverpool pẹlu.

O gba goolu wọle sawọn ni ifẹsẹwọnsẹ akọkọ akọkọ rẹ tako Liverpool.

Lasiko to n gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ kan fun ikọ orilẹede rẹ Sweden loṣu kẹsan an ni Isak fi itan rẹ ṣeṣe.

“O ṣeni laanu pe itan rẹ to fi ṣeṣe yoo ṣediwọ fun un. A ko lero pe a o le ri Alex lori papa ki idije ife ẹyẹ agbaye to bẹrẹ”

Idije ife ẹyẹ agbaye yoo bẹrẹ logunjọ oṣu kọkanla ni orilẹede Qatar.

Diego Jota lori papa

Oríṣun àwòrán, instagram/diogoj_18

Jota fi ẹsẹ pa lasiko ifẹsẹwọnsẹ Liverpool pẹlu Manchester City lọjọ Aiku.

Akọnimọọgba ikọ Liverpool, Jurgen Klopp sọ fun awọn akọroyin pe Diego Jota to ṣeeṣe ko ṣoju fun Portugal ni ife ẹyẹ agbaye ko ni lee kopa nitori o ti fi ẹsẹ ṣeṣe.

Diego Jota náà yóò pàdánù kíkópa ní ìdíje World Cup

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Wọn gbe Jota kuro lori papa lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ naa n mura ati pari ni papa iṣire Anfield.

Iroyin ayọ ibẹ ni pe Jota ko ni ṣe iṣẹ abẹ lati tọju ohun to n ṣe e naa.

Jurgen Klopp ṣalaye lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Westham United pe “iroyin ti ko dara to nipa Diogo.”

Klopp ko sọ pato asiko ti Jota yoo pada, amọṣa o ni ipa ti ko ṣee fẹnusọ ni aisi lori papa rẹ yoo mu ba ikọ naa