Òǹwòran bọ́ọ̀lù tó kú di 174, 191 ló fara gbọgbẹ́

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà di ìjà ìgboro, ọlọ́pàá méjì wà lára àwọn tó kú, wọ́n ba ọ̀pọ̀ ọkọ̀ wa jẹ́ - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Awọn eeyan to farapa

Akọtun iroyin to n tẹ wa lọwọ ti fidi rẹ mulẹ pe eeyan to ti ba isẹlẹ titẹ ara ẹni pa to waye lorilẹede Indonesia ti di mẹrinlelaadọsan (170) bayii.

 Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe eeyan ọgọfa lo ku ninu isẹlẹ naa nigba ti awọn eeyan ọgọsan fara pa.

 Amọ ileesẹ ọlọpaa ni Indonesia ti fidi rẹ mulẹ pe iye eeyan to ku ninu isẹlẹ naa ti to mẹrinlelaadọsan.

 Wọn fikun pe eeyan mọkanla tun ti kun iye awọn to fara pa, ti apapọ wọn si ti di igba din mẹsan (191).

Àkọlé fídíò, Scores killed at Indonesia football match

Aarẹ Indonesia ni ki wọn dawọ idije Liigi duro

Awọn ero iworan lori papa

Aarẹ orilẹede Indonesia, Joko Widodo ti wa pasẹ pe wọn dawọ gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu liigi lorilẹede naa duro titi ti iwadii yoo fi pari lori isẹlẹ naa. Awọn fidio to jade sita lati papa isere bọọlu ti isẹlẹ naa ti waye se afihan bawọn onworan ere bọọlu ti wọn n sare lọ sori papa lẹyin ti adari ere bọọlu naa fọn fere ikẹyin pe ere ti pari. Ninu ifẹ́sẹwọnsẹ naa si ni ẹgbẹ agbabọọlu to n gbalejo idije naa ti ni ami ayo meji, ti awọn alatako rẹ si ni ami ayo mẹta. Idi si ree tawọn ọlọpaa to wa nibẹ fi yin afẹfẹ taju taju lati dena ija igboro to le waye tori ijakulẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Awọn ero iworan lori papa

Isẹlẹ naa ti di ija igboro lati se yin afẹfẹ tajutaju – Ileesẹ ọlọpaa

Nigba to n salaye idi ti isẹlẹ itẹraẹnipa naa se waye, ileesẹ ọlọpaa naa ni isẹlẹ naa ti di ti ija igboro ni.

 “Se ni wọn n kọju ija sawa ọlọpaa, ti wọn si n ba awọn ọkọ wa jẹ.” Nico Afinta tii se ọga ọlọpaa lẹkun ila oorun Java lo sọ bẹẹ.

 Afinta fikun pe awọn ọlọpaa meji gan wa lara awọn eeyan to ba isẹlẹ naa rin.

 “Amọ a fẹ yan pe kii se gbogbo awọn eeyan naa lo lọwọ ninu idaluru naa... amọ ẹgbẹrun mẹta awọn onworan to ya wọ ori papa ọhun lo fa ija igboro yii.

 O fikun pe “Se ni awọn onworan yii n ya lọ sẹnu ọna abajade papa isere naa, bi wọn si se n pọ ni o n soro fun wọn lati ri afẹfẹ mi.”

 Awọn fidio to wa lori ayelujara nipa isẹlẹ itẹraẹnipa naa lo se afihan awọn ero to n fo ori ogiri lati sa lọ.

 Bakan naa ni awọn fidio kan se afihan ọpọ oku to wa nilẹ kaakiri.

Awọn ero iworan lori papa

A kan n gbọ pau pau pau ni – Awọn Osojumikoro

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Muhamad Dipo Maulana, tii se ẹni ọdun mọkanlelogun, toun naa wa ni papa isere naa sọ fun akọroyin BBC ni Indonesia bi ọrọ naa se jẹ.

 Maulana ni lẹyin ti idije naa wa sopin, awọn ololufẹ ikọ agbabọọlu Arema ya wọ ori papa lati kọju ija si ikọ alatako agbabọọlu naa amọ tawọn ọlọpaa da wọn lọwọ kọ, ti wọn si n na wọn.

 O ni idi ree ti ọpọ awọn onworan ere bọọlu naa fi ya wọ ori papa lati fi ẹhonu wọn han lori isẹlẹ yii, ti ohun gbogbo si di rogbodiyan.

 “Awọn ọlọpaa to mu aja lọwọ pẹlu Police with dogs, ate idaabo bo ara wọn atawọn Sọja bọ siwaju.” Malauna sọ fun BBC

 Bakan naa lo fikun pe oun tun gbọ ti iro agolo afẹfẹ tajutaju to le ni ogun n dun, eyi ti wọn n yin mọ awọn onworan naa ninu papa isere idaraya ọhun.

 “Ariwo naa pọ, se la n gbọ pau, pau, pau! Se ni ariwo yii n dun leralera, to si n sare wa.

 Ariwo naa pọ to bẹẹ gẹ, to si n doojukọ gbogbo ibi tawọn eeyan duro si.”

 O ni oun ri awọn eeyan ti wọn n sa kijo-kijo kiri, ti ibẹru bojo si gbalẹ kan, bẹẹ ni ọpọ wọn ko ri afẹfẹ mi simu daadaa bi wọn se fẹ tete sa jade kuro ninu papa isere idaraya naa.

 Osojumikoro naa ni ọpọ awọn ọmọde ati agbalagba lo wa lara awọn eeyan ti afẹfẹ tajutaju naa ba .

Òǹwòran bọ́ọ̀lù 120 kú, 180 míì gbọgbẹ́ ní pápá ìṣeré bọ́ọ̀lù

Aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe o kere tan eniyan to le ni ọgọfa ti ku lasiko ti awọn eniyan bẹrẹ si ni tẹ ara wọn pa ni papa iṣere bọọlu ni orilẹede Indonesia.

Iṣẹlẹ titẹ ara ẹni mọlẹ naa waye lẹyin ti awọn ọlọpaa fẹ afẹfẹ taju taju si awọn ololufẹ ere bọọlu.

O kere tan, eniyan ọgọjọ lo farapa ninu iṣẹlẹ naa lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Arema FC jakulẹ lasiko ifẹṣẹwọnṣẹ pẹlu Persebaya Surabaya in agbegbe East Java.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

Adari eto aabo lorilẹẹde naa ṣalaye pe awọn to wa si papa iṣere naa kọja ẹgbẹrun mẹrin ti papa iṣere naa le gba.

Fido ṣafihan bi awọn ololufẹ erebọọlu ṣe yabo ori papa lọgọọrọ lẹyin ti wọn fun fere pe ifẹṣẹwọnṣẹ ti pari.

Eyi lo mu ki awọn ọlọpaa fin tajutaju, ti awọn eniyan si bẹrẹ si ni tẹ ara wọn mọlẹ.

Awọn eniyan si koju ija si awọn ọlọpaa, ti meji si wa lara awọn to ku.

Bakan naa ni awọn eniyan to n tiraka lati jade pọ si, ti wọn si bẹrẹ si ni tẹ ara wọn mọlẹ, ti ọpọ si gba ibẹ lọ.

Aarẹ orilẹede naa ti paṣẹ pe ko gbọdọ si ifẹṣẹwọnṣẹ kankan ni orilẹede Indonesia tit iwadii yoo fi pari lori iṣẹlẹ naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Njẹ iru iṣẹlẹ yii ti waye ri?

Iṣẹlẹ yii jẹ ọkan gboogi to milẹ titi ninu awọn ijamba ori papa to ti waye kaakiri agbaye.

Ni ọdun 1964, o kere tan eniyan ọọdunrun lo papoda, ti eniyan to le ni ẹgbẹrun kan si farapa lasiko erebọọlu olympic ni ifẹwọnṣẹ laarin Peru ati Aregentina ni Lina.

Bakan naa ni Ilẹ Gẹẹsi lọdun 1989, ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool mẹtadinlọgọrun ni wọn tẹ pa lasiko ifẹṣẹwọnṣẹ ni papa iṣere Hillsborough ni Sheffield.