Ọ̀pọ̀ èèyàn yínmú sí ọ̀rọ̀ Buhari ní àyájọ́ òmìnira

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò àti aráàlú ní Buhari ń mú òmúlòmú ni
Awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ oselu alatako ati awọn ọmọ Naijiria kan ti n yinmu si ọrọ ti aarẹ Muhammadu Buhari sọ lọjọ ayajọ ominira Naijiria.
Lara awọn ẹgbẹ oselu alatako naa la ti ri ẹgbẹ oselu Labour ati PDP ti wọn yọ suti ete si ọrọ aarẹ, eyi to ni ijọba oun ti se ọpọ aseyọri lori aleefa.
Bẹẹba gbagbe, aarẹ Muhammadu Buhari lo kede ninu ọrọ to bawọn ọmọ Naijiria sọ ni ayajọ ominira pe bi eeyan ko ba yin oun, oun yoo yin ara oun nidi awọn aseyọri ti oun ti se.
Aarẹ ni ijọba oun ti se gudugudu meje ati ya ya mẹfa nidi gbigbogun ti iwa ajẹbanu ati sise wo ilu basubasu, ipese ilera to poju owo atawọn nnkan miran.
Se aabo dara si ni abi o buru si lati 2015 ti Buhari gori aleefa – PDP n beere
Amọ nigba to n sọ ero rẹ lori ikede aarẹ Buhari naa, agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu PDP, Debo Ologunagba ni ofuuftu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun ninu, ni ọrọ aarẹ naa.
PDP ni kawọn ọmọ Naijiria se agbeyẹwo awọn isẹlẹ to n waye lati fi se odiwọn ohun ti Buhari sọ nitori ẹni ti yoo sa purọ, nii sọ pe ẹlẹri oun wa ni ọrun.
PDP ni se a le sọ pe orilẹede Naijiria ti ni aabo to pegede si lati ọdun 2015 ti aarẹ Buhari ti gba ijọba ni abi aabo n buru si?
Ẹgbẹ oselu alatako naa ni yoo dara ki aarẹ Buhari jẹ ki eto idibo to n bọ lọ gaaraga bo se yẹ nitori awọn ọmọ Naijiria ko le se suuru mọ lati ri ẹyin isejọba Buhari lọdun 2023.
Ko si ileri kankan ti aarẹ se lasiko ipolongo ibo rẹ lọdun 2015, to se amusẹ rẹ - Ẹgbẹ ajafẹtọẹni
Nigba to n ba iwe iroyin Punch sọrọ, aarẹ tẹlẹ fun ẹgbẹ to n ja fẹtọ ọmọniyan, Malachy Ugwumadu salaye pe ofo ọjọ keji ọja ni awọn ileri ti aarẹ Buhari se ko to dori aleefa.
Malachy ni ki ijọba Buhari to gba ọpa asẹ lọdun 2015, ọpọ ileri to se ni ko tii mu wa si imusẹ, koda, ko mu ẹyọ kan sẹ ninu rẹ.
Amọ o ni yatọ si eyi, ohun ti awọn ọmọ Naijiria ri ni pe owo ọpọ eroja n lọ soke, eto aabo mẹhẹ, ti iwa ajẹbanu si di tọrọ fọn kale.
Buhari n mu omulomu ni, ohun to n waye yatọ si ohun to n sọ – APGA
Nigba toun naa n se agbeyẹwo ọrọ ti Buhari sọ lati ki awọn ọmọ Naijiria ku ayajọ ominira, alaga ẹgbẹ oselu alatako APGA, Victor Oye ni irọ nla ni.
Oye ni aarẹ kan n mu omulomu ni nitori ohun to n waye lorilede Naijiria yatọ gedegede si awọn aseyọri ti aarẹ mẹnuba.
Amọ o yan pe ireti ti awọn ọmọ Naijiria n foju sun bayii ni pe ki aarẹ mu ileri rẹ to kede laipẹ yii sẹ pe oun yoo rẹyin awọn agbebọn, ti yoo ba fi di osu kejila ọdun 2022.
Buhari ko mọ ohun to n waye ni Naijiria, orilẹede mii lo n gbe - Sowore
Lero tiẹ, oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu AAC, Omoyele Sowore ni Buhari ko mọ ohunkohun to n waye ni Naijiria.
“Ọpọ igba ni oun ti maa n kede pe orilẹede miran tabi aye mii ni aarẹ Buhari n gbe, ti ko si mọ nnkan kan to n sẹlẹ lorilẹede yii.”
Ìyà tó ń jẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń dùn mí lára gan, ìdí tí mo fi fẹ́ kí ASUU padà sẹ́nu iṣẹ́ rèé - Ààrẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency
Aarẹ Buhari ti tun paa laṣẹ fun awọn adari ile ẹkọ giga fasiti pe ki wọn ni kawọn olukọ pada si kilaasi kiakia.
Aarẹ n sọ eyi lara ọrọ to sọ ni owurọ ayajọ ọjọ ominira orilẹede Naijiria to si ni oun ni imọlara iya to n jẹ awọn ọmọ Naijiria.
"Mo ni lati jẹwọ fun yin pe iṣe ti idena ṣe n wa fun ilọsiwaju lawọn ile ẹkọ giga wa n dun mi lara gidi gan mo si n lo anfani ọjọ ominira yii lati tun tẹnu mọ pipe fun ki awọn ọmọ ẹgbẹ Academic Staff Union of Universities (ASUU) pada si kilaasi nigba ti a si n fi da wọn loju pe ojutuu yoo wa fun ọrọ to n ka wọn lara laarin ohun to wa nilẹ".
Aarẹ Buhari ni iṣejọba yii n ri ilọsiwaju ninu kikoju awọn ọrọ yii to ti wa nilẹ fun o le ni ọdun mọkanla o si ni ijọba apapọ yoo tẹ́iwaju lati ṣakojọ labẹle ati lẹyin odi lati ya owo lu ẹka eto ẹkọ "ki awọn ọmọ waa lee kẹkọ yanju ati mimọ oniruuru iṣẹ ọwọ tori ẹkọ ni atọna akọkọ fun idagbasoke ọrọ aje ati ipese iṣẹ."
"A ṣiṣẹ́ ṣiṣẹ́, àmọ omi pọ̀ ju ọkà lọ lórí ìpèníjà Nàìjíríà- Ààrẹ Buhari sọ ohun tó fàá"

Oríṣun àwòrán, Google
Aarẹ Buhari ni oun jẹjẹ oun si muu ṣẹ pẹ̀lu ifarajin lati mu ọgọrun miliọnu ọmọ Naijiria kuro ninu ìṣẹ́ laarin ọdun mẹwa.
Gẹgẹ bi awọn eeyan agbaye ṣe n ki orilẹede Naijiria ku oriire lonii ayajọ ọjọ ominira orilẹede naa, Aarẹ Muhamadu Buhari ti fi ọrọ rẹ ṣe ajimuna fawọn ọmọ Naijiria.
Ninu ọrọ naa ti atupalẹ kikọ rẹ hande latọwọ olugbaninimọran aarẹ lori iroyin ati ọrọ to kan araalu, Femi Adesina lori ayelujara, aarẹ Buhari ni pẹlu ọkan ọpẹ si Ọlọrun loun fi n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ tori oun lo fun oun lanfani ati ṣe adari lori orilẹede nla yii ni asiko ipenija.
“Tori mo mọ pe eyi ni yoo jẹ ọrọ ikẹyin mi fun ọjọ ominira gẹgẹ bi aarẹ yin, mo n ba ọgọọrọ ọmọ Naijiria to gbagbọ ninu mi sọrọ ti wọn si gbaruku ti mi ninu bi mo ṣe n dari orilẹede yii ti gbogbo araalu ti ni anfani kan naa lati ṣe aṣeyọri ti wọn fẹ”.

Oríṣun àwòrán, Google
Aarẹ Buhari ni iwuri lo jẹ fun oun pe itan oun ninu itan Naijiria kii ṣe aṣiri kankan, akitiyan rẹ, ijakulẹ ati aṣeyọri rẹ lati di aarẹ ti ọpọlọpọ dibo yan lọdun 2015.
“Nigba naa, bo tilẹ jẹ pe mo sọọ pe oke to wa niwaju mii yi ga ju ṣugbọn mo ṣe ipinu lati mu igbega ba ọrọ aje, koju iwa ajẹbanu ati koju ija si iṣoro aabo eyi si tun gba agbara sii pẹ̀lu ifarajin mi lati mu ọgọrun miliọnu ọmọ Naijiria kuro ninu ìṣẹ́ laarin ọdun mẹwa”.
Aarẹ ni tori pe awọn mọ iṣẹ to wa niwaju awọn, a wa akoko lati farabalẹ kojumọ ṣiṣe atunto ọrọ aje nipa wiwa ọna abayọ to dara lawọn apa ibi to ṣe koko ni ipele ijọba apapọ ati awọn ipele kekeke.
Iwa Jẹgudujẹra
Aarẹ ni lara awọn ibi ti ijọba oun ti ni ilọsiwaju ni gbigba iwa jẹgudujẹra danu eyi to ti rapala wọ gbogbo kọlọfin ibi idagbasoke orilẹede.
“A ro ileeṣẹ to koju iwa jẹgudujẹra lagbara lati lee koju iwa yii bẹẹ si ni a tun rii pe atilẹyin wa fun wọn labẹnu eyi to mu iṣẹ ya lati ri ọpọlọpọ owo gọbọi ti awọn eeyan ti ko pamọ si awọn orilẹede mii gba pada”. Aarẹ ni igbesẹ yii ṣi n tẹsiwaju awọn ko si ni sinmi.
Ipenija aabo
Aarẹ Buhari ni ohun ti ijọba oun ṣe lati le koju iṣoro aabo ni iṣẹ adọgbọnṣe ti awọn ṣe to mu adinku ba igbesunmọmi ni awọn apaa Ila Ooru-Ariwa, awọn ajijagbara Niger Delta, ija ẹlẹyamẹya ati wahala ẹsin lawọn igun kọọkan ni Naijiria to fi mọ awọn iṣoro mii to n dun mọhuru mọ orilẹede Naijiria.
Ọrọ Aje
“Akitiyan wa lati ṣe atunto ọrọ aje farahan ninu ipenija ifasẹyin gboogi meji to fi Naijria lakalaka”.
Ẹwẹ, aarẹ sọ oniruuru idamu ti Naijiria ti foju ri ni ti ọrọ aje to si tun sọ igbesẹ ti wọn gbe fun apẹẹrẹ mimu idiwọ ọlọdun pipẹ kuro lọna awọn to wu lati wa dokoowo ni ẹka po rọbi ati afẹfẹ gaasi eyi to si hande ninu fifọwọ si abala ofin ileeṣẹ ipọnpo ti ọdun 2021. Lara awọn koko mii ti aarẹ Buhari mẹnu pe ijọba oun ti ṣe aṣeyọri ni: Ẹka eto ọgbin Okoowo kekeke ati eto ẹyawo Imọ ẹrọ ibaraẹnisọrọ eyi ti yoo ran pipa owo ilẹ okere wọle. Aarẹ tun sọ pe bi awọn ṣe n pa ina iṣoro aabo to doju kọ Naijiria lati ọjọ pipẹ ni awọn mii to tun ṣajoji si orilẹede yii bẹrẹ si ni yọju paapaa bii ijinigbe, fifiyajẹni, pipa awọn alaiṣẹ, janduku to si ni gbogbo eyi ni awọn oṣiṣẹ alaabo n koju.
“Mo ni imọlara iya ti awọn ọmọ Naijiria n la kọja mo si n fi daa yin loju pe ai kaarẹ yin ati suuru yin ko ni ja si asan tori ijọba yii yoo tun fi agbara kun agbara lati doju kọ gbogbo ipenija yii.”















