'Ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ mi ló wú mi lórí láti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe àgbélẹ̀rọ ẹsẹ̀ àti ọwọ́ fún àwọn ọmọ tí kò le rìn'

Oríṣun àwòrán, CRYSTAL CHIGBU
“Nigba ti a bii, ko ni egungun lẹsẹ eyi si jẹ ipenija nla fun emi ati ọkọ mi'
Crystal Chigbu lo ṣalaye yii lori ọrọ ọmọ rẹ ti wọn bi laisi egungun ẹsẹ.
“Nigba ti wọn sọ fun mi pe wọn maa ge ẹsẹ ọmọ mi ni, mo kọkọ sare jade, mo sa lọ patapata. Beulah ni akọbi ọmọ mi. Mi o gbọ iru nnkan bayii ri. Ko si ninu iran mi."
Crystal joko sọrọ pẹlu BBC Pidgin lori bi igbe aye ẹbi oun ati ẹbi rẹ ṣe yipadayipada nipasẹ iriri rẹ ati ti ọmọ rẹ ti wọn pada ge lẹsẹ ti ko wa lee rin mọ.
“Ṣaaju akoko yii, mi o tii ri eeyan ti wọn bi pẹlu nnkan bayii ri laye mi tabi ti wọn ge lẹsẹ.
Mo maa n ri awọn to ni ọwọ kan tabi ẹsẹ kan loju popo ṣugbọn nko tilẹ roo ripe o lee wa pada kan emi naa. O fi mi logbologbo. Mo bi Ọlọrun leere ẹṣẹ mi.”
‘L’ọjọ ti mo kọkọ riti ọmọ mi fi ẹsẹ ara rẹ duro, mo bu si ẹkun’

Oríṣun àwòrán, CRYSTAL CHIGBU
Ni awujọ to jẹ pe awọn eeyan ti maa n da si ọrọ ti ko ye wọn pẹlu idẹyẹsi awọn akanda lọpọlọpọ, Crystal sọrọ lori ipenija to koju lori ọrọ ọmọ rẹ.
O sọ pe nigba ti wọn ge ẹsẹ ọmọ oun obinrin, ọpọ eeyan lo n sọ ọ kaakiri pe eṣẹ awọn lo pọ si Ọlọrun lo fimu ki Ọlọrun gbe iru ipenija bẹẹ ko wọn loju.
“Ki wọn to fun ọmọ mi ni agbelẹrọ ẹsẹ eyi to fi n rin kaakiri bayii ti awọn kan si maa n beere idi ti awọn ṣi fi maa n gbe ọmọ to ti dagba bayii kiri.
Wọn ni a kan fẹ ba a jẹ ni. Ọpọ igba ni mi o si ki n mọ esi ti maa fun wọn.”

Oríṣun àwòrán, CRYSTAL CHIGBU
Crystal sọ pe lọjọ akọkọ ti oun ri ọmọ oun to duro funra rẹ lẹyin ti wọn fi agbelẹrọ ẹsẹ si ẹsẹ rẹ, omije bọ loju oun.
“O wọ aṣọ ileẹkọ rẹ, o duro pẹlu ẹsẹ ti wọn ṣefun un naa , ni mo ba bẹrẹ si nii sunkun ti mo si tun n rẹrin papọ lẹsẹ kan naa nitori pe inira leyi jẹ fun oun ati ọkọ oun.
Eyi ni Crystal so eyi gan lo wu oun lori lati ṣe iranwọ fun awon omode to wa ni ipo kan naa ṣugbọn ti awọn naa nkoju ohun ti oun pẹlu koju
Wo bi Crystal ṣe bẹrẹ si ni ran awọn ọmọde miiran lọwọ

Oríṣun àwòrán, CRYSTAL CHIGBU
Ajọ iranwọ kan to n pese aloku agbelẹrọ ẹsẹ at’awọn ohun irinna mirqn fawọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju odun mejidinlogun lọ ni Crystal Chigbu gbe kalẹ bayii.
Ọmọ rẹ obinrin ti won bi laini egungun ẹsẹ lo bi agbekalẹ ajọ iranwọ yii.
“A rii pe awọn ọmọ kan naa wa ti wọn bi wọn bee naa tabi ti wọn ni ijamba to ge ẹsẹ wọn tabi ọwọ wọn.
Mo bẹrẹ si nii ba awọn obi wọn sọrọ lati mọ ọna ati mu aye dẹrun fun wọn.”
Crystal ni oun pinnu lati fi iṣẹ oojọ oun silẹ lati gbaju mọ riran awọn ọmọ ti wọn ge ọwọ tabi ẹsẹ wọn lọwọ nitoripe o n mu inu oun dun.
“ Inu mi maa n dun lati ri pe awọn ọmọde miran ti n ni ẹsẹ lati fi rin.
Ona ti a n gba ṣe agbelẹrọ ẹsẹ naa da lori rironu lori ohun ti yoo ṣe ọmọde ti a fẹ lo o fun lanfani.”
O ni awọn ni awọn akọṣẹmọṣẹ to mọ nipa rẹ lati rii daju pe awọn agbelẹrọ ẹsẹ ti wọn ba ṣe naa yoo duro deede fun awọn ọmọ to fẹ lo o.
“Nigba ti awọn ọmọde naa ba ti ye ẹsẹ naa wo, a o gbiyanju lilo rẹ lati rii daju pe o ṣe rẹgi pẹlu wọn. O le maa jẹ ọwọ tabi ẹsẹ ti wọn ni tẹlẹ, ṣugbọn nigba tí ọmọ naa ba rin, ẹ o mọ boya nnkan kan ku diẹ kaaro lara rẹ.”
O salaye siwaju sii pe awọn ọmọ miran n si lee gba bọọlu, sare tabi ṣe awọn ohun miran pẹlu agbelẹrọ ẹsẹ tiwọn.
'Ọmọ to ba n lo agbelẹrọ ẹsẹ tabi ọwọ si le e gbe igbe aye irọrun ti too si gbadun aye rẹ.'

Oríṣun àwòrán, CRYSTAL CHIGBU
Crystal Chigbu ṣalaye pe ọmọ to ba n lo agbelẹrọ ẹsẹ tabi ọwọ si le e gbe igbe aye irọrun ti yoo si gbadun aye rẹ gẹgẹ bi iriri toin ṣe lọ.
O ni ọmọ oun ṣi n luwẹ, gun kẹkẹ at’awọn ere idaraya miran.
“A ti ri lara awọn ọmọ ti a ti ṣe iranwọ fun ti wọn ti sọ pe awọn fẹ di dokita, amofin ati bẹẹbẹ lọ lọjọ iwaju lai f’ọkan si pe ipenija wọn lee di ala ọjọ ọla wọn lọwọ.
Gẹgẹ bi ọrọ ti Crystal Chigbu sọ fun BBC, o ti le ni ọọdunrun awọn ọmọ to ti ran lọwọ pẹlu agbelẹrọ ẹsẹ tabi ọwọ lati igba ti ajọ iranwọ to gbe kalẹ ti bẹrẹ.
O tun fi kun un pe igba miran wa ti oun maa n fẹ kọkọ ran awọn ọmọ to ti de ọjọ ori ati lọ sile iwe , ati lati wo bi ipenija awọn miran ṣe ta koko si ki oun to lati lee mọ ọmọ ti oun yoo kọkọ ran lọwọ.
Ohun to yẹ ki o mọ ki ọmọ rẹ to le maa lo agbelẹrọ ọwọ tabi ẹsẹ

Oríṣun àwòrán, CRYSTAL GHIGBU
Fun ọmọde kan lati lee lo agbelẹrọ ọwọ tabi ẹsẹ ri won n pe ni ‘prosthetic’ yoo nii ṣe pẹlu ohun ti wọn fẹ ṣe.
Agbelẹrọ ọwọ tabi ẹsẹ yii jẹ arọpo fun awọn ẹya ara wọn kan ti wọn padanu yala nipasẹ ijamba ni tabi gige e kuro
Igbesẹ akọkọ ni fun awọn obi tabi alagbatọ ọmọ bẹẹ lati joko sọrọ pẹlu awọn ri yoo pese agbelẹrọ ẹya ara yii lati lee mọ ohun gan ni pato ti ọmọ wọn fẹ lo o fun lari le mọ eyi to se rẹgi fun un ni lilo.
Fun apẹrẹ: bi ọmọ ba ni ẹsẹ mejje, ohun elo agbelẹrọ ti wọn nilo yoo wa fun ati lee rin.
Ohun miran ti wọn tun ni lati kiyesi ni ọjọ ori wọn. Irufẹ awọn ohun elo agbelẹrọ ẹsẹ tabi ọwọ ti wọn nilo tun nii. Ṣe pẹlu ọjọ ori wọn.
Awọn agbelẹrọ ẹsẹ tabi ọwọ maa n ran awọn akanda ọmọ lati tubọ fi irọrun gbe igbe aye wọn amọṣa yoo gba wọn lakoko diẹ lati mọọ lo daadaa.
Nitori naa wọn yoo nilo ayẹwo atigbadegba, ati boya atunṣe diẹ lawọn ibi kan tabi omiran lati jẹ ko dun un lo, ko si tun wulo fun wọn daadaa.












