Ìrọ́ ìbọn ń dún lákọ láti gba ìjọba padà lọ́wọ́ ológun tó gbàjọba Burkina Faso

Aworan

Oríṣun àwòrán, EPA

Ọgagun Ibrahim Traoré to gbajọba lọwọ ọga rẹ ti ni wọn n gbiyanju lati gba ijọba lọwọ ohun pada.

Ibrahim Traoré fi ẹsun kan ikọ Ọmọgun orilẹede Faranse pe awọn ni wọn gbalejo Ogagun Paul-Henri Damiba, ti oun yọ kuro ni ipo bii jiga.

Amọ orilẹede Faranse ti ni awọn ko da si iṣẹlẹ ọhun.

Bakan naa ni iro ibọn n dun lakọlakọ ni olu ilu Burkina Faso, Ouagadougou pẹlu awọn ọkọ baalu, ti wọn si n kọja ni ori awọn eniyan.

Awọn afẹhọnuhan tako iditẹgbajọba naa ti dana si iwaju Ile iṣẹ ijọba Ilẹ Faranse to wa lorilẹede Burkina Faso, ti ijọba Faranse si bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ naa.

Ologun ti gba ijọba ni ẹẹmẹjọ lati ọdun 1960, ti Burkina Faso ti gba ominira

Aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn afẹhonuhan danu sun ilesẹ asoju ilẹ Faranse ni Bobo-Dioulasso

Ninu ọrọ rẹ, orilẹede Faranse ni awọn ko da si ikọ ologun to gbajọba nibẹ amọ awọn yoo daabo bo ikọ ọmọogun ilẹ Faranse to wa nibẹ lai si ewu fun wọn.

Bakan naa ni wọn ni awọn ti ṣi ojuko pajawiri si Ouagadougou fun awọn araalu.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni awọn ologun ti opopona to wọ ilu naa, ti wọn si ti awọn ṣọọbu to wa ni ṣiṣi pa.

Ni ilu nla keji lorilẹede naa, Bobo-Dioulasso ni wọn tun ti dana sun ile iṣẹ orilẹede Faranṣe to wa nibẹ.

Ori tẹlifisọn ni awọn araalu ti gbọ wi pe ijọba ologun ti gbakoso orilẹede naa.

Ọgagun Ibrahim Traore ni idi ti oun fi gba ijọba ni pe ijọba ologun to wa nibẹ ko lee bori ipenija eto aabo to dẹnukọlẹ nibẹ.

Orilẹede Burkina Faso ti wa labẹ aṣẹ ijọba ologun fun saa mẹjọ lati igba ti orilẹede naa ti gba ominira lọwọ orilẹede Faranse ni ọdun 1960.

US ni ki awọn eniyan rẹ ṣọra ṣe ni Burkina Faso

Aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

Nibayii, orilẹede Amerika ti kesi awọn eniyan rẹ lati kiye sara gidi gidi ni orilẹede Burkina Faso pẹlu wahala to n waye nibẹ.

Bakan naa ni wọn parọ wa si wọn lati maṣe rin kaakiri lasiko yii.

Ninu ọrọ tirẹ, orilẹede Faranse naa kilọ fun awọn eniyan rẹ to le ni ẹgbẹrun mẹrin to wa nibẹ.

O ni ki wọn duro sibi ti wọn ba wa lasiko yii, ki wọn ma si maa rin kiri olu ilu naa, Ouagadougou.

Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ológun gba ìjọba ní Burkina Faso

Awọn Ologun to ditẹ gbajọba ni Burkina faso

Oríṣun àwòrán, RADIO TÉLÉVISION DU BURKINA

Lọjọ Ẹti ni iroyin lu sigboro agbaye pe ọkan lara awọn ọmọ ogun orilẹede Burkina Faso ti kede lori mohunmaworan apapọ orilẹede naa pe oun ti ditẹ gba ijọba lọwọ olori ijọba ologun to wa lorilẹede naa, ọgagun Paul-Henri Damiba.

Ibrahim Traore to lewaju iditẹgbajọba naa ṣalaye pe nitori aikunoju oṣuwọn rẹ lati kapa awọn agbesunmọmi alakatakiti ẹsin Islam to n ṣọṣẹ lorilẹede naa lawọn ṣe gba ijọba lọwọ rẹ.

O ni awọn yẹ aga mọ Kọnẹli Damiba nidi “lati lee parapọ mojuto ohun to jẹ gbogbo eeyan orilẹede Burkina Faso logun, ninu eyi ti mimojuto ọrọ abo ilu ati orilẹede naa.”

Bakan naa lo tun kede pe gbogbo aala orilẹede naa, yala ti ilẹ ni tabi ofurufu ni yoo wa ni titipa titi di ọjọ miran ọjọ ire, ti gbogbo eto to nii ṣe pẹlu oṣelu yoo si lọ rọọkun naa.

Ni ọ̀oṣu kinni ọdun yii ni ọgagun Damiba ditẹ gba ijọba lọwa ijọba oloṣelu to wa lorilẹede naa lori awawi pe awọn lee dẹkun gulegule awọn agbesunmọmi alakatakiti ẹsin Islam to n koju oro si orilẹede naa.

Amọṣa, iṣejọba rẹ ko ri ọgbọn da si ikọlu awọn alakatakiti naa. Lọjọ Aje, ṣọja mọkanla lawọn agbebọn ṣi pa lasiko ti wọn n ṣọ ọkọ awọn eeyan kan lẹkun ariwa orilẹede naa.

Ṣaaju lọjọ Ẹti, Ọgagun Damiba rọ awọn eeyan orilẹede naa lati fi ọkan balẹ lẹyin ti wọn gbọ iro ibọn lolu ilu orilẹede naa.

Igba keji ti iditẹgbajọba yoo waye lorilẹede yii niyi laarin oṣu mẹjọ.

Ki lo ti ṣẹlẹ lati igba yii wa?

Ọgagun Damiban ba awọn Ologun kan sọrọ lorilẹede Burkina faso

Oríṣun àwòrán, Reuters

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn agbẹnusọ fun ijọba ti wọn gbaga ni idi rẹ naa, Lionel Bilgo sọ fun ileeṣẹ akoroyinjọ AFP lọjọ Ẹti pe ọrọ sisan owo oṣu awọn ologun lo fa “wahala” ati pe Ọgagun Damiba ti n ba wọn jiroro lori rẹ.

Amọṣa lati irọlẹ ọjọ Ẹti, ko si ẹni to mọ ibi ti Damiba wa.

Bi o tilẹ jẹ wipe awọn ati orilẹede France kii ye ni ajọṣepọ to danmọran, sibẹ awọn to sun mọ awọn aṣoju orilẹede naa ṣalaye fun ileeṣẹ redio RFI pe ọgagun Damiba ko si ni ọdọ wọn

Amọṣa ajọ ikan orilẹede Afirika, AU ti pe fun idapada ijọba tiwantiwa o pẹju oṣu keje ọdun 2023. Bakan naa ni alaga ajọ AU naa, Moussa Faki Mahamat ke sawọn ologun nibẹ “lati dẹkun gbogbo iwa rogbodiyan ati idunkukulaja mọ awọn araalu, ileeṣẹ ajafẹtọ gbogbo”

Ṣaaju ni ajọ orilẹede to wa lẹkun iwọ oorun Afirika, ECOWAS ti koro oju si iditẹgbajọba naati wọn si n sọ pe oun “ ṣi n tẹnumọ aidunnu oun si eto iyipada yoowu ti ko ba lọwọ idibo ninu”

Orilẹede Amẹrika ni tirẹ sọ pe inu oun ko dun si ohun to n ṣẹlẹ lorilẹde Burkina Faso, to si n rọ awọn eeyan rẹ lorilẹede naa lati fi irin wọn mọ niwọn nibẹ.

Bakan naa ni orilẹede France gbe irufẹ ikilọ bẹẹ sita fun awọn eeyan rẹ bii ẹgbẹrun mẹrin to wa ni olu ilu orilẹede naa, iyẹn Ouagadougou. “A n pe fun alaafia latọdọ awọn olukopa ninu iṣẹlẹ yii,”

Ki lawọn koko ohun ti ijọba ologun tuntun ni Burkina Faso sọ?

Ikọ ologun to gbajọba ni Byurkina Faso naa, ti wọn pe orukọ ara wọn ni movement patriotic pour la sauvegarde et la restauration, MPSR, sọ pe awọn ti ṣepade lọjọ Ẹti tii ṣe ọgbọn ọjọ oṣu kẹsan an ọdun 2022 nibẹ lawọn si ti fimọ ọkan pe ki wọn gba ipo lọwọ Ọgagun Paul Herny Damiba ki Kaputeni Traore Ibrahim si bọ si ipo rẹ.

Wọn wa kede fun agbaye pe awọn nnkan wọnyi lawọn ti gbe igbesẹ le lori:

  • Idaduro iwe ofin orilẹede naa
  • Idaduro eto idajọba pada fun alagbada
  • Ituka ileegbimọ aṣofin
  • Titi gbogbo aala orilẹede naa lori ilẹ ni tabi ofurufu bẹrẹ lati agogo mejila oru ọgbọn ọjọ oṣu kẹsan an titi di ọjọ miran ọjọ ire.
  • Ofin Konile o gbele bẹrẹ lati agogo mẹsan an alẹ si marun owurọ.
  • Idaduro gbogbo eto oṣelu
  • Idaduro gbogbo iṣẹ awọn ajọ ajafẹtọ
  • Ipe yoo jade si awọn aṣoju ẹka gbogbo lawujọ orilẹede naa laipẹ lati gbe ilana tuntun kalẹ fun dida ijọba pada fun alagbada ti wọn yoo si yan aarẹ tuntun fun orilẹede Burkina Faso, eyi to lee jẹ alagbada tabi ologun.