Buhari, ìhàlẹ̀ lásán ni ìdúnkòkò rẹ̀, a kò padà sí kíláàsì – ASUU yarí

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ni Naijiria, ASUU ti seleri pe iyanṣẹlodi yoo tẹsiwaju titi ti ijọba yoo fi wa ọna abayọ si ọrọ yii.
Aarẹ ẹgbẹ ASUU, Emmanuel Osodeke lo sọ bẹẹ lẹyin ti aarẹ Buhari kesi ẹgbẹ naa lati fopin si iyanṣẹlodi wọn , ki wọn si pada si ẹnu iṣẹ wọn.
Amọ̀ Osodeke, ninu lẹta to kọ sawọn olukọ, ni awọn ko ni da idunkoko ijọba lohun ayafi ti wọn ba dahun si ibeere wọn, ki wọn si san owo oṣu awọn oṣiṣẹ.
Bakan naa lo ni awọn ko tapa si aṣẹ ileẹjọ to ni ki awọn wọle pada nitori awọn ti gba ileẹjọ kotẹmilọrun lọ.
O ni nitori awọn ti lọ si ileẹjọ kotẹmilọrun naa, awọn le boju wẹyin mọ lori iyanṣelodi naa.
"A ti fi ye ijọba pe awa kii ṣe atẹmẹrẹ ti wọn le ṣe baṣubaṣu"
‘’Iyanṣelodi yii ti fẹrẹ pe oṣu mẹjọ, ti mo si dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ti wọn ko wẹyin bi o tilẹ jẹpẹ ijọba kọ lati san owo oṣu fun wa mọ.’’
‘’A ti fi ye ijọba pe awa kii ṣe atẹmẹrẹ ti wọn le ṣe baṣubaṣu tabi ti wọn le dunkoko mọ.’’
‘’Eleyii ti mu ki eso rere maa jade, ti ijọba si n gbiyanju lati ba wa sọrọ.’’
Laarin ọṣẹ meji, a ti jijoro pẹlu adari ile aṣojuṣofin, Femi Gbajabiamila.
Igbagbọ wa si ni pe Aarẹ Buhari yoo da wa lohun ni kiakia ti wọn ba ti gbe adehun naa de ọdọ rẹ.
Bakan naa lo fikun un pe inu awọn ko dun pe awọn akẹkọọ wa ni ile lai ṣe nkankan.
Ẹgbẹ ASUU wa rọ gbogbo awọn ti ọrọ kan lati sa ipa wọn lati fi opin si iyanṣelodi naa lai fi iya jẹ awọn olukọ bakan naa.

Fasiti Nasarawa paṣẹ fun awọn akẹkọọ lati wọle pada

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ akẹkọọ fasiti ipinlẹ Nasarawa ni kawọ akẹkọọ pada sile ẹkọ
Wayi o, ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni fasiti ipinlẹ Nasarawa, Keffi (NSUK) ti kesi awọn akẹkọọ lati gbọ aṣẹ adari fasiti pe ki wọn pada si ileẹkọ.
Aarẹ ikọ awọn akẹkọọ fasiti Nasarawa, Naajim Gbfwi fi ero wọn lede ni ilu Keffi.
Lẹyin ti awọn alaṣẹ ileẹkọ naa fi atẹjade sita ni Ọjọ kejidinlọgbọn, Oṣu Kẹsan an pe ki awọn akẹkọọ pada si ileẹkọ nitori kilasi yoo bẹrẹ pada ni kiakia.
Eyi lo mu ki ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa rọ awọn akẹkọọ lati pada si ileẹkọ lati bẹrẹ eto ẹkọ wọn pada.
Bakan naa ni wọn kesi ẹgbẹ ASUU lapapọ lati maṣe tapa si igbeṣẹ wọn nitori awọn nifẹ lati pada si ẹnu ẹkọ wọn.
Amọ Alaga ẹgbẹ ASUU ni fasiti Nasarawa, Ọmọwe Samuel Alu ti bu ẹnu atẹ lu aṣẹ fasiti ọhun pe ki awọn akẹkọọ wọle pada.
Alu ni ko si ohun to jọ bẹ ẹ nitori awọn olukọ ko ni wọle pada ayafi ti ijọba ba pari iyanṣelodi naa, ti wọn si san owo oṣu wọn.















