'Lóòtọ̀ ni òsͅìsͅéͅ 21 kú ní fásitì Calabar láàrín osͅù méje tí ASUU bẹ̀rẹ̀ ìyansͅéͅlódì'

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

O kere tan awoͅn olukoͅ fasiti to le ni ogun ti padanu eͅmi woͅn ni fasiti Calabar laarin osͅu meje ti eͅgbeͅ osͅisͅeͅ ASUU ti beͅreͅ iyansͅeͅlodi.

Osͅu Keji, oͅdun 2022 ni eͅgbeͅ osͅisͅeͅ ASUU beͅreͅ iyansͅeͅlodi lori eͅsun pe ijoͅba apapoͅͅ koͅ lati mu adehun sͅe peͅlu awoͅn olukoͅ .

Bakan naa ni woͅn beͅreͅ atunsͅe ni awoͅn fasiti kaakiri orileͅede Naijiria.

Amoͅ ijoͅba kan an ni ipa fun woͅn lati pada si ileeͅkoͅ ki woͅn to le san owo oṣu fun wọn.

Ijọba n ṣamulo ofin pe eͅnikeͅni ti ko ba sͅisͅeͅ ko ni gba owo osu.

Sͅe lootoͅ ni osͅisͅeͅ fasiti 21 ti Calabar padanu eͅmi woͅn laarin osͅu meje ti ASUU ti gunle iyansͅeͅlodi?

LAipẹ yii ni iroyin gbode pe o kere tan oͅjoͅgboͅn ati oͅmoͅwe to le ni ogun ti gbeͅmi mi laarin osͅu meje.

Alaga eͅgbeͅ awoͅn osͅisͅeͅ fasiti ni Calabar, John Edor lasiko to n ba BBC soͅroͅ ni lootoͅ ni awoͅn olukoͅ agba fasiti naa jade laye.

‘’Amoͅͅ awoͅͅn oͅjoͅgboͅn, oͅmoͅwe bii meͅwaa ni awoͅn to jeͅ oͅmoͅ eͅgbeͅ ASUU, awoͅn yoku jeͅ osͅisͅeͅ fasiti ti kii sͅe olukoͅ.’’

‘’Airi ounjeͅ jeͅ, itoͅju to peye nitori woͅn ko san owo osͅu awoͅn osͅisͅeͅ yii jeͅ oͅkan lara ohun to sͅekupa wọn.’’

‘’ O sͅoro lati soͅ wi pe iyansͅeͅlodi ASUU lo fa iku woͅn, amoͅ nigba ti woͅn ko ba gba owo osͅu, ko si bi woͅn sͅe maa toͅju ara woͅn.’’

‘’Bakan naa ni ijoͅba gboͅdoͅ gboͅ ohun ti a n soͅ, owo osͅu wa kii seͅ titi woͅn, awoͅn ko ni woͅn ni owo ilu, nitori naa ko bojumu ki woͅn soͅ wi pe olukoͅ ti ko ba sͅisͅeͅ, ko ni gba owo osu.’’

‘’Iya ati isͅeͅ ti a ko ri iru reͅ ri lo n jeͅ awoͅnͅ olukoͅ’’

Ninu oͅͅroͅͅ reͅͅ, agbeͅͅnusoͅͅ osͅisͅeͅͅ ASUU naa ni iya n jeͅ awoͅn olukoͅ lati igba ti iyansͅeͅlodi yii ti beͅreͅ, nitori ijoͅba koͅ lati san owo osͅu woͅn.

O ni iru ifiyajeͅni ti a ko ri iru reͅ ri ni ki woͅn masͅe san owo osͅu osͅisͅeͅ fun osͅu meje gbako.

‘’Oͅpoͅloͅpoͅ awoͅn olukoͅ woͅn yii ni woͅn n toͅroͅ jeͅ, ti woͅn kesi eͅbi ati ara lati ran woͅn loͅwoͅ.’’

‘’Nkan ti ijoͅba sͅe ko bojumu rara nitori awoͅn koͅ ni woͅn ni owo ilu, ti woͅn fi wa n fi iya jeͅ awoͅn eniyan loͅna aitoͅ, lai bikita.

Laipeͅ yii ni ileeͅjoͅ to n risi oͅroͅ karakata pasͅeͅ fun awoͅn osͅisͅeͅ fasiti lati pada si eͅnu iseͅ leͅyin osu meje , amoͅ eͅgbeͅ osͅisͅeͅ naa yari kanleͅ pe afi ti ijoͅba ba san owo osu awoͅn lasiko iyansͅeͅlodi oͅhun.