'Méjì lára àwọn tó pa àbúrò mi ti kọ́kọ́ wá mu ọtí ní 'hotel' rẹ̀ lọ́sàn-án'

Oríṣun àwòrán, Caleb Owolabi
Ẹni to jẹ ẹgbọn oniṣowo kan to jẹ ọmọ Naijiria, ṣugbọn to n gbe nilẹ America, Ayorinde Owolabi, ti sọrọ lori iku rẹ.
Ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni awọn ajinigbe pa ọkunrin naa ati akẹkọọ Fasiti Lautech kan nilu Ogbomoso.
Iroyin sọ pe ninu ile itura Ọgbẹni Owolabi ni wọn ti ji oun ati akẹkọọ Lautech naa, Racheal Opadele to jẹ oṣiṣẹ nibẹ gbe.
Wọn pa awọn mejeeji lẹyin ti wọn gba owo itusilẹ lọwọ ẹbi wọn.
Ninu ọrọ to sọ fun BBC, ẹgbọn oloogbe Ayorinde Owolabi, Alagba Caleb Owolabi sọ pe meji lara awọn to pa aburo oun ati oṣiṣẹ rẹ naa, ti kọkọ wa a mu ọti nile itura rẹ.
O ni "nkan to jẹ ka mọ ẹya ti wọn ti wa ni pe meji lara wọn ti kọkọ wa mu ọti nile itura naa lọsan, koda wọn sọ pe awọn fẹ ẹ gba yaara.
"Ọmọbinrin ti wọn gbe pẹlu aburo mi, Rachael, lo ta ọti fun wọn, boya nitori ẹ ni wọn ṣe ji oun naa gbe."
Alagba Caleb ṣalaye pe ọgọrun miliọnu Naira ni wọn kọkọ beere fun, amọ awọn ko miliọnu marun-un lọ lẹyin ọjọ kẹrin ti wọn gbe wọn.
O ni ẹni to gbe owo naa lọ ṣalaye pe bi wọn ṣe gba owo naa, ni wọn bẹrẹ si sọ ede ti oun ko gbọ. Lẹyin naa si ni wọn bẹrẹ si yinbọn mọ awọn to wa ni ahamọ wọn, ẹni to gbe owo lọ, ati ọlọkada to gbe e lọ.
Ẹni to gbe owo lọ nikan ni ko kú ninu awọn mẹrẹẹrin.
Oloogbe Owolabi ti n gbe nilẹ America lati ọdun 1986, to si ma n wa sile lati wo awọn eeyan rẹ ati awọn okowo to n ṣe ni Naijiria.
Botilẹ jẹ pe ẹbi oloogbe fi ẹsun kan pe awọn eeyan kan lati ẹya Fulani lo ṣe iṣẹ ibi naa, ileeṣẹ ọlọpaa ko fidi eyi mulẹ.
Bakan naa ni wọn ko tii ri afurasi kankan mu lori iṣẹlẹ ọhun.



