Kí ni àwọn fijilanté ń fi AK47 ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún? Akeredolu fún ìjọba àpapọ̀ lésì

Mi ò ní sinmi àyàfi tí ààbò tó péye báwà fún àwọn ará ìlú mi

Akeredolu atoi Buhari

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Gómínà ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu ti ní òun kò ní ye pariwo àyàfi tí ààbò tó gbópọn bá wà fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ òun àti ilẹ̀ Yorùbá lápapọ̀.

Akeredolu nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Richard Olatunde fi síta ní ìpinnu Ààrẹ láti dènà àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tí kìí ṣe ti ìjọba àpapọ̀ láti má lo ìbọn ìgbàlódé kò dára tó

Ó ní àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ rẹ̀ Garba Shehu fi síta pé àwọn kò ní fi ààyè gba àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò yàtọ̀ sí ti ìjọba láti lo àwọn ohun ìjà ìgbàlódé kò sí ní ìbámu pẹ̀lú ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra lọ́wọ́ yìí.

Ó fi kun pé gbogbo àwíjàre tí Shehu ń sọ lórí ìdí tí àwọn fijilanté Katsina tí wọ́n ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú AK47 ṣùgbọ́n tí ìjọba àpapọ̀ kọ̀ láti gba ẹ̀ṣọ́ Amotekun láti ṣe bẹ́ẹ̀ kìí ṣe ohun tó ṣe é gbọ́ sétí.

Gómìnà Akeredolu ní ìròyìn tí iléeṣẹ́ TVC fi síta ṣàfihàn ibi tí àwọn fijilanté Katsina ti ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ìbọn AK47 lọ́wọ́ àti pé tí kò bá ṣe wí pé wọ́n fẹ́ lò ó, kí ni wọ́n ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú rẹ̀ sí.

Bákan náà ló ìbéèrè tí òun ń bèèrè ni pé ṣe àwọn fijilanté náà yóò dá ìbọn náà padà lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tán àti pé to ló buwọ́lùú fún wọn láti fi kẹ́kọ̀ọ́?

Ó tẹ̀síwájú pé láti ìgbà tí ìròyìn ọ̀hún ti gbòde, ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina kò jìyàn gbogbo ẹ̀sùn tí òun fi kàn wọ́n, tí òun kò sì mọ ìdí tó fi jẹ́ pé Garba Shehu wa sọ ara rẹ̀ di agbẹnusọ ìpínlẹ̀ Katsina.

Gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ló nílò láti máa lo ìbọn ìgbàlódé

Akeredolu tẹnumọ pé òun tí òun ń jà fún ni pé gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó bá wà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ní àǹfàní láti máa lo àwọn ìbọn ìgbàlódé èyí tọ jẹ́ wí pé ohun ni àwọn ọ̀daràn ń lò láti máa fi ṣiṣẹ́ ibi wọn.

Ó fi kun pé ọwọ́ lásán kò ṣèé kojú àwọn oníṣẹ́ ibi tí wọ́n ń ṣàkóbá fún ààbò Nàìjíríà àti pé ìjọba ní ojúṣe láti dá ààbò tó péye bo àwọn ará ìlú láì sí tàbítàbí kankan nínú.

Ó ṣàlàyé pé òun ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé gbogbo ọ̀nà ni òun ma gbà láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ òun.

Ètò ààbò Nàìjíríà ti mẹ́hẹ kọjá bẹ́ẹ̀, ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ló le tán ìṣòro ààbò

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, Akeredolu ní ẹnu gbogbo àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ ló kò lórí ìpinnu náà àti pé àwọn lọ́balọ́ba ẹkùn àríwá náà kí wọn lẹ́yìn.

Ó ní ohun tó kù ni kí ìjọba àpapọ̀ náà gbọ ìpè àwọn kò sí fọwọ́ sí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀.

Ó tẹ̀síwájú pé àsìkò yìí gan ló yẹ ki ìjọba kojú gbogbo àwọn ọ̀daràn tó ń da omi àláfíà ìlú láàmú nítorí ènìyàn kò le máa ṣe nǹkankan náà ní gbogbo ìgbà kó wá máa retí èsì tàbí àbájáde tó yàtọ̀.

Ìpínlẹ̀ kankan tó fi mọ́ Katsina tẹ́ n pariwo kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ra ìbọn fún iléèṣẹ́ aláàbò - Buhari

Buhari and Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Aketi/Buhari

Ṣaájú ni a ti mú ìròyìn wá fún-un yí pé Ijọba apapọ Naijiria ti sọ pe oun ko fun ipinlẹ kankan ni Naijria lagbara lati ra ohun ija oloro funra rẹ fun eto abo.

Aarẹ Muhammadu Buhari lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan loju opo Twitter ijọba apapọ Naijiria.

Atẹjade ọhun ni ọọfisi Aarẹ fi lede lẹyin ọsẹ kan ti gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, kede pe oun yoo ra ibọn fun ẹṣọ alaabo Amotekun.

Bakan naa ni ko tii ju ọjọ kan ti eeyan bii ẹẹdẹgbẹrin darapọ mọ ikọ naa l’Ondo.

Ninu atẹjade naa to fi si oju opo Twitter ileeṣẹ aarẹ lọjọ Iṣẹgun, ijọba apapọ sọ pe oun ko fun ijọba ipinlẹ kankan laṣẹ lati ra ohun ija oloro fun ikọ abo abẹle rẹ, yala ipinlẹ Katsina ni o tabi ipinlẹ mii ni Naijiria.”

“Labẹ iṣejọba yii, a ti jẹ ko ye gbogbo araalu pe ko si ẹnikẹni to laṣẹ lati gbe ibọn AK-47, ẹni to ba si ni irufẹ ibọn naa lọwọ gbọdọ jọwọ rẹ fun ijọba.”

“Labẹ ofin, ọọfisi ileeṣẹ to n ri si eto abo, NSA, nikan lo le fun ẹnikẹni laṣẹ lati lo ohun ija oloro, iyẹn lẹyin to ba ti kọkọ gba aṣẹ lati ọọfisi Aarẹ.”

Ijọba apapọ ni lodi soi ohun ti Akeredolu sọ pe awọn ẹṣọ abẹle ipinlẹ Katsina n gbe ibọn AK-47, ṣe ni awọn eeyan naa lo ibọn ọhun lati ṣe idanilẹkọọ lasiko eto kan, kii ṣe pe wọn fẹ maa lo.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

A ko ni la oju wa silẹ ki wọn maa pa awọn eeyan wa – Akeredolu

Ẹwẹ, ṣaaju ni gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kọkọ sọ pe Ijọba apapọ n ṣe ojuṣaju laarin awọn ipinlẹ to jọba le lori.

O ni oun ri fidio ibi ti awọn ẹṣọ abẹle ipinlẹ Katsina ti n gbe ibọn AK-47, bẹẹ ijọba apapọ kọ ki awọn gomina ilẹ Yoruba ra irufẹ ibọn kan naa fun ikọ Amotekun.

Aketi ni “A fẹ ki gbogbo araalu mọ pe, ko si bi ọbọ ṣe ṣ’ori ti inaki naa ko ṣe o.”

“Ijọba ipinlẹ Ondo ti ṣetan bayii, gẹgẹ bii ojuṣe rẹ labẹ ofin, lati ra ibọn fun abo awọn eeyan rẹ.”

“Igbesẹ yii ṣe pataki, paapaa lasiko yii ti awọn agbesumọmi n ra ibọn bo ṣe wu wọn.”

O pari ọrọ rẹ pe “Ijọba ipinlẹ yii ko ni la oju rẹ silẹ ki awọn agbesumọmi maa pa awọn eeyan wa ni ipakuta lai wa nnkan ṣe si.”

“A o daabo bo awọn eeyan wa.”