Irú àìsàn wo ló n ṣe Baba Ijesha, tó fi nílò ìtọ́jú pàjáwìrì lọ́gbà ẹ̀wọ̀n?

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, THEWILL NIGERIA

Oṣere tiata Yoruba to wa lọgba ẹwọn niluu Eko lori ẹsun pe o ba ọmọde ṣe aṣemaṣe, Olanrewaju James, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, ti ke gbajare pe aisan buburu kan n ba oun finra n inu ahamọ to wa bayii.

Eyii lo mu ki oṣere naa ke si awọn ọmọ Naijiria lati ṣe iranlọwọ fun oun.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, akẹgbẹ rẹ, Yomi Fabiyi sọ pe lootọ ni apanilẹrin naa n ṣaisan ninu ahamọ, o si nilo itọju ni kankan.

Yomi Fabiyi ni “Ootọ ni pe Baba Ijesha n ṣaisan, aarẹ yẹn ti wa lara wọn ko to di pe wọn lọ sinu ahamọ.”

“Lẹnu igba ti mo ba wọn sọrọ bii ọsẹ to kọja, bi wọn ṣe n dun… mo ni ki wọn lọ si ile iwosan to wa ninu ibẹ nitori emi ni igbagbọ pe o yẹ ki wọn lẹtọtọọ si itoọju.”

“Boya nigba ti wọn lọ, wọn ko ri itọju to peye nibẹ ni wọn ṣe ke gbajare sita, amọ ootọ ni pe agara da wọn.”

Irufẹ aisan wo lo n ṣe Baba Ijesha?

Fabiyi sọ pe eyii to ju ninu aisan naa ko ṣẹyin ikọlu ti awọn kan ṣe si oṣere naa ninu ile Princess nigba ti wọn kọkọ fẹsun biba ọmọde lopọ kan an.

O ni “Eyii to jẹ olori ibẹ ni ibi ti wọn ni wọn ti la igi mọ awọn lori ninu ile Princess.”

Gẹgẹ bii ohun ti Fabiyi sọ, o ni Baba Ijesha sọ pe wọn la igi mọ oun lori nile Princess nigba ti wọn fẹsun kan oun, ori naa lo si n yọ lẹnu.

Fabiyi pari ọrọ rẹ pe, ọkan lara awọn aburo Baba Ijesha to jẹ dọkita ti n gbiyanju lati yọju si ọgba ẹwọn lati ba awọn alaṣẹ ọrọ lori ipo ilera rẹ ati ọna abayọ.

Ọjọ karun un, oṣu Keje, ọdun 2022 yii ni ile ẹjọ ran Baba Ijesha lẹwọn lẹyin to jẹbi mẹrin ninu ẹsun mẹfa ti wọn fi kan, eyii to ni ṣe pẹlu ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọde.