EFCC mú òṣìṣẹ́ ìjọba Kwara tó fún ọmọ ijọ́ 23 ní ayédèrú iṣẹ́

Aworan afurasi ti Efcc mu

Oríṣun àwòrán, EFCC

Kele ti gbe arabinrin kan ti ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria EFCC sọ pe o n lu awọn eeyan ni jibiti nipa fifun awọn to n wa iṣẹ ni ayederu iwe igbanisiṣẹ.

Orukọ arabinrin naa gẹgẹ bi ajọ EFCC ti ṣe gbe sita ninu atẹjade kan ni Oyawoye R. Olajumoke Fafemi.

Wọn lawọn ti wọ lọ siwaju ile ẹjọ giga to wa ni Ilorin lori ẹsun onigun mẹrin to da lori iwa jibiti nipa igbanisiṣẹ ati eto awọn alalaaji.

O kere tan awọn eeyan mẹtalelogun lo ti pin iwe igbanisiṣẹ fun to si gba owo lọwọ wọn ni ipinlẹ Kwara.

Gbogbo wọn si jẹ ọmọ ile ijọsin ti wọn lawọn n wa iṣẹ.

EFCC ṣalaye pe oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ eto inawo ni ẹni ọdun mẹtalelaadọta naa jẹ.

Gẹgẹ bi alaye ti wọn ṣe, awọn ọmọ ile ijọsin Christ Apostolic Church to wa ni Offa lo fi na ẹburu gba owo lọwọ wọn lori irọ pe oun yoo ba wọn wa iṣẹ.

O ni iṣẹ yi yoo jẹ iṣẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Kwara tabi ko si jẹ pẹlu ijọba apapọ.

''Iwadii wa fihan pe Fafemi fun awọn eeyan mẹtalelogun yi pata ni iwe igbanisiṣẹ.''

''O kọ sinu rẹ pe ijọba ipinlẹ Kwara ati ijọba apapọ ti fun n ni iṣẹ koda o fi iye owo oṣu ati ipo ti wọn gba wọn si, sinu lẹta wọn''

Efcc ko ṣalaye dedee iye owo to gba ati boya awọn ti gba owo naa pada lọwọ arabinrin naa.