Ayoola Ajibade: Ilé-ẹjọ́ fẹ̀sùn lílu jìbìtì $500,000 kan ọmọ Nàíjíríà ní Canada

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilé-ẹjọ́ kan lorilẹede Canada ti fẹsun jibiti owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta owo dọla, $500,000, kan ọmọ Naijiria kan, Ayoola Ajibade.
Ilé-ẹjọ́ naa salaye bi afurasi ọhun to n wa ọkọ Uber, ṣe gbiyanju lati lu ilu Bridgewater ni Nova Scotia ni jibiti $500,000.
Ileẹjọ ni Ajibade fi ara rẹ pe ọga agba ileeṣẹ kan nilu Nova Scotia.
O wa gba ilu naa lamọran lati san $490,930 sí ẹkun ile ifowopamọ Scotia kan to wa ni Brampton.
- Ọmọ ilú Osogbo bíi Hushpuppi, Dele Ewe rí ẹ̀wọ̀n oṣù 30 he ní Amerika fún ẹ̀sùn 419
- Bí EFCC ṣe mú ayédèrú ọ̀gágun sọ́jà Bolarinwa tó tún ní ẹ̀sùn jìbìtì owó N270m
- Gbájúẹ̀ tó ń fi ọ̀rọ̀ ifẹ́ lu àwọn obìnrin ní jìbìtì ní Kano kó s'ọ́wọ́ Ọlọ́pàá
- Wo àwọn báńkì tó wà lẹ́yìn àwọn olówó èlé bí MMM
- Afurasí mẹ́jọ tó tẹ ayédèrú ₦98m àti $1.5m wọ gàù àjọ DSS
Gẹgẹ bi iṣẹ iwadii ṣe sọ, banki Scotia wa tọpasẹ rẹ lọ si ilu Bridgewater ati ileeṣẹ Dexter Construction ti Ajibade ní ibẹ loun ti n ṣiṣẹ.
Wọn ní Ajibade lo ni apo asunwọn to ni ki wọn sanwo si ni banki naa amọ kii ṣe oṣiṣẹ ileeṣẹ Dexter Construction, gẹgẹ bo se sọ.
Ajibade fún ra rẹ sọ fun ileẹjọ pe ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Andrew ni Naijiria lo ni ki oun ṣe iranwọ fun oun lori ati ra okoowo ni China.
Ileẹjọ ni Andrew jẹ ọrẹ Joshua, to jẹ ọkunrin kan ti Ajibade ti ba ṣiṣẹ pọ ri.
Sugbọn Ajibade ko mọ orukọ baba Joshua, bẹẹ ni ko mọ adiresi ile rẹ.
Ajibade jẹri pe lootọ ni oun fun Andrew ni apo asunwọn owo oun lai mọ ohun to fẹ fi se.
Leyin naa ni Andrew ni kí oun yẹ akaunti oun wo ki oun si fi $180,000 ranṣẹ si China ko le fi ra àwọn irinṣẹ kan.
Ajibade bu s'ẹkun nile ẹjọ, o ni oun ko mọ pé jibiti ni ọrọ naa yoo jasi.
Pẹlu gbogbo awijare rẹ, agbẹjọro olupẹjọ ni iwa jibiti nla ni Ajibade ju.
Ile ẹjọ yoo dajọ lori iru ijiya to tọ si Ajibade laipẹ.














