Ṣé lóòtọ́ ni wọ́n fipá bá ọmọ ọdún mẹ́wàá tí wọ́n rí òkú rẹ̀ ní Eko lòpọ̀?

Àwòrán ẹni tí wọ́n ń fipá balòpọ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọrọ lori oku ọmọdebinrin kan ti wọn deede ri ni agbegbe Ayobo nipinlẹ Eko.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ naa, Benjamin Hundeyin sọ fun BBC pe lootọ ni awọn ri oku naa ṣugbọn iwadii n tẹsiwaju lati fidi ohun to ṣokunfa iku ọmọde naa mulẹ.

Ṣaaju ni oṣerebinrin tiata Yoruba, to tun jẹ adẹrinposonu, Damilola Adekoya ti ọpọ eeyan mọ si Princess ti kọkọ gbe ọrọ yi soju opo ayelujara to si ni wọn fipa ba ọmọde naa lo pọ ni.

O darukọ ọmọde naa to si ni iya to bi ọmọ naa ti lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Ayobo ṣugbọn wọn ko jẹ ki o foju ri oku ọmọ rẹ.

Ninu fọnran fidio to fi si oju opo Instagram rẹ, Princess kesi alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Eko taa ba sọrọ pe ko tete wa nkan ṣe si ọrọ yi.

Bẹẹ la ri arabinrin kan ti o pe ara rẹ ni iya ọmọde naa.

O ṣalaye fun Princess ninu fidio naa pe wọn fipa ba ọmọ rẹ lo pọ ni ati pe wọn pa ọmọdebinrin ẹni ọmọ odun mẹwaa yi.

Amọ Ọgbẹni Hundeyin sọ pe awọn ko le sọ boya ifipabanilopọ waye ṣugbọn ṣa awọn ri oku ọmọdebinrinkan ati pe awọn ti n ṣe iwadii lori ohun to ṣokunfa iku rẹ.

O ni kete tawọn ba pari iwadii ni awọn yoo fi to awọn akọroyin leti bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.

Awọn eeyan kan jẹri pe wọn fi ipa ba ọmọ naa lopọ ni

Gẹgẹ bi a ti ṣe sọ saaju, alukoro ọlọpaa Benjamin Hundeyin sọ pe awọn ti mu awọn afurasi kan ṣugbọn ko darukọ iye wọn.

Amọ loju opo Princess to fi fidio si, eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ @Hrh King Adedamola O loju opo Instagram sọ pe oun wa ni agọ ọlọpaa ti wọn gbe ẹjọ yi lọ ati pe ole ni eeyan mẹrinla ti wọn ti mu lori ọrọ yi.

O ni ''bi apẹrẹ awọn onile ladugbo,obinrin olori ile ijọsin kana ti awọn ọmọ ile ijọsin wa lara awọn ti wọn mu wọn si ti gbe eeyan mẹfa ninu wọn lọ si Panti''