‘Èmi kọ́ ni mo ń jí ènìyàn gbé, tèmi ni láti fi ilé woͅn hàn'

Oríṣun àwòrán, The Nation
Arakunrin afurasi ajinigbe, Lyon Ewa ti sͅalaye ipa ti o ma n ko lasiko ijinigbe.
Lyon ni oͅwoͅ teͅ leͅyin ti ileesͅeͅ oͅloͅpaa nipinleͅ Bayelsa ni awoͅn ti mu ogbontagiri ajinigbe to n da ipinleͅ naa ru, ti oͅwoͅ si teͅ woͅn lasiko ti woͅn ji oͅga banki gbe ni Yenagoa.
Oͅga banki ti woͅn jigbe naa ti orukoͅ reͅ n jeͅ Danjuma Emeije lo jeͅ oͅga reͅ teͅleͅ.
Ile awoͅn ti woͅn ba feͅ jigbe nikan ni mo ma n fihan , emi koͅ lo n fi woͅn han

Oríṣun àwòrán, The Nation
Lyon Ewa ninu oͅroͅ reͅ lasiko ifoͅroͅweroͅ peͅlu awoͅn akoͅroyin ni oun ki n sͅe ajinigbe, ile awoͅn ti woͅn ba feͅ jigbe nikan ni oun maa n sͅafihan reͅ.
Amoͅ o ni lootoͅ ni oun gba 3.5 million naira lasiko ijinigbe nitori oun darukoͅ reͅ ati ibi to n gbe fun woͅn.
''Emi ko lo ji woͅn gbe, ile woͅn nikan ni mo fihan'’
'’ A n wa oͅkoͅ lo ni mo si soͅ fun woͅn pe ile oͅga mi teͅleͅ niyii, lobatan'’
Amoͅ oͅkan lara afurasi to jeͅ olubasͅisͅeͅpoͅ reͅ ti orukoͅ reͅ n jeͅ Emma ni ko si otitoͅ kankan ninu oͅroͅ ti Lyon soͅ nitori awoͅn joͅ sͅisͅeͅ poͅ ni.
'Koda owo tireͅ lo poju. bawo ni eͅni ti ko moͅ nkankan nipa reͅ fi gba owo goͅboͅi?
'’Oun gan an lo soͅfun wa pe ki a lo gbe oͅga oun teͅleͅ nitori o yoͅ oun leͅnu isͅeͅ, nitori oͅloͅla ni.'
Wo bí ọwọ́ ṣe tẹ afurasí ajínigbé tó n fi owó bùgá lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu afurasi ogbontarigi ajinigbe kan to ma n fi ọlá rẹ ṣe fọri-fọri lori ayelujara.
Oṣiṣẹ ile ifowopamọ ni ọpọ eeyan mọ John Lyon si, to si ma n gba awọn eeyan ni imọran lati jara mọ isẹ ni gbogbo igba to ba fi aworan tabi fidio si ori ayelujara.
Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Bayelsa, Asimi Butswat, sọ fun BBc pe ilu Abuja ni ọwọ ti tẹ Ọgbẹni Lyon, ṣugbọn wọn ti gbe e wa si ipinlẹ Bayelsa fun iwadii.
Ko din ni iṣẹlẹ ijinigbe mẹwaa, ti wọn fi gba owo nipinlẹ Bayelsa, ti ileeṣẹ ọlọpaa
sọ pe ko ṣẹyin ikọ ajinigbe Lyon. Amọ, oun kọ ni olori ikọ naa.
Lati opin ọsẹ ni fidio kan to ṣafihan afurasi naa ti wa ni ori ayelujara, ninu eyi ti wọn ti fi ṣẹkẹṣẹkẹ de e lọwọ.
Botilẹ jẹ pe Ọgbẹni Lyon ko tii jẹwọ ni gbangba, a ri ninu fidio naa ni ahamọ ọlọpaa, to si n tọrọ aforijin lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ.
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo si ti n fi iyalẹnu han lori bi ọwọ ṣe tẹ ẹ, ti awọn kan si n ṣapejuwe afurasi naa gẹgẹ bi ẹni to lawọ, to ma n fun awọn eeyan ni ẹ̀bùn.














