'Ká má a jí owó ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ìwé yíyí ló da ààrin èmi àti ‘speaker’ Ogun rú'

Àkọlé fídíò, Ká má a jí owó ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ìwé yíyí ló da à[rin èmi àti ‘speaker’ rú
'Ká má a jí owó ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ìwé yíyí ló da ààrin èmi àti ‘speaker’ Ogun rú'
Olori ile aṣofin Ogun ati igbakeji rẹ

Awuyewuye to n waye laarin olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Olakunle Oluomo ati igbakeji rẹ, Oludare Kadiri, ko ti dopin.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022, ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Najiria, EFCc, mu olori ile aṣofin naa fun ẹsun kiko owo ilu jẹ.

Ọwọ tẹ ẹ ni papakọ ọkọ ofurufu Murtala Muhammed nilu Eko.

Wọn fi ẹsun kan Ọgbẹni Oluomo ati awọn aṣofin mii, pe wọn yí iwe, wọn si tun ṣe mago-mago iwe akọsilẹ owo ile aṣofin naa.

O lo ọjọ diẹ ni ahamọ ajọ naa, ki wọn to o pada yọnda rẹ, botilẹ jẹ pe iwadii ṣi n lọ lori ẹsun naa.

Diẹ lara awọn ọmọ ile aṣofin naa, to fi mọ olori ile funra rẹ si lo gbagbọ pe, ti wọn si fi ẹsun kan igbakjei pe oun lo ditẹ pẹlu EFCC lati parọ ole mọ Ọgbẹni Oluomo.

Lẹyin ọrọ naa ni awọn ọmọ ile aṣofin ati olori wọn, paṣẹ fun igbakeji rẹ ati aṣofin mii pe awọn da wọn duro fun igba diẹ.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, igbakeji ile aṣofin naa, Ọgbẹni Oludare Kadiri, sọ pe olori ile fi orukọ oun fọwọ si awọn iwe owo kan to to ọgọrun miliọnu Naira ti oun ko mọ nipa rẹ.

Bakan naa lo sọ pe awọn igbesẹ olori ile naa le sọ oun di eero ẹwọn lọjọ iwaju ni oun ṣe kesi EFCC.

Ṣugbọn ninu ọrọ rẹ, Aṣofin Oluomo to jẹ olori ile sọ pe fifi ẹjọ sun EFCC tako ofin ihuwasi awọn aṣofin.