Baba Ijesha rí ẹ̀wọ̀n he lórí ẹ̀sún ìfipábá ọmọdé lọ̀pọ̀

Ile-ẹjọ pataki kan ti Ikeja ti ní gbajugbaja oṣere Olanrewaju James, ti a n pe ni Baba Ijesha jẹbí esun ifipa banilopo ọmọ ọdun merinla kan.
Adajo Oluwatoyin Taiwo, ninu idajo wakati meji lojo òní , da Baba Ijesha lebi fun iwa aisedede si omo kan, ilokulo ibalopo, ati igbidanwo ifipabanilopo ibalopo.
Taiwo, sibẹsibẹ, da bàbà ìjèsà lare lórí esun Sexual assault by Penetration àti ti kika ọkan ati Attempted Sexual Assault by penetration.
Ni akoko gbigbe iroyin yii, ẹjọ naa ti duro fun iṣẹju diẹ fun Adajọ láti ṣe ìdájọ́.
Ó ti bẹ̀rẹ̀! Baba Ijesha gúnlẹ̀ sí ilé ẹjọ́, wo bí ẹ̀sùn ìfipá b’ọ́mọdé lòpọ̀ ṣe di ràǹtò dé ibi ìdájọ́ tí yóò gbọ́ lónìí

Oni loni n jẹ ẹni a bẹ lọwẹ! Ero ti n kun si ile ẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹsun nipa ibalopọ ni Ikeja ipinlẹ Eko nibi ti wọn yoo ti ṣe idajọ gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Olanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha.

O ti di ọdun to kọja bayii ti igbẹjọ naa bẹrẹ lẹyin ti akẹgbẹ Baba ijesha, Princess Commediene wọ ọ lọ sile ẹjọ nitori pe ẹrọ ayaworan CCTV to wa ninu ile rẹ tu aṣiri bi Baba Ijesha ṣe n fi ọwọ riun ọmọdebinrin ti Princess jẹ alagbatọ fun lara ati ni kake gẹgẹ bi igbaradi lati baa ni ajọṣepọ.
Awọn alaṣẹ fi Baba ijesha han nile ẹjọ eyi to si pada di jọ ijọba ipinlẹ Eko lori ẹsun mẹfa ọtọọtọ ti wọn fi kan an to da lori ṣiṣe ọmọde baṣu-baṣu, sisọ ọmọde di polofo, ilọkulọ ibalopọ nipasẹ kiki nkan ọmọkunrin bọ oju ara ọmọdebinrin, gbigbiyanju ati ba ọmọde naa lopọ ati ilọkulọ ibalopọ.
Amọṣa o, lati ọjọ ti igbẹjọ yii ti bẹrẹ ni Baba Ijesha ti n sọ niwaju adajọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.
Ni ọjọ ti wọn farahan nile ẹjọ gbẹyin ko to di oni ti ile jọ da, ati olupẹjọ ati olujẹjọ lo ti fi ọrọ kikọ wọn silẹ.
Agbẹjọro agba Naijiria, Dada Awosika sọ lọjọ naa fún ile ẹjọ pe ki wọn ma ṣe ka ẹri “exhibit A, eyi to jẹ ti inu ẹrọ ayaworan CCTV ti olupẹjọ gbe wa si.
O ni ki ile ẹjọ da ẹri naa nu lori alaye pe wọn ti kọwọ bọ bi fidio naa ṣe ri.
Ẹwẹ, Oludari ikọ awọn agbẹjọro olupẹjọ fun ipinlẹ Eko, Ọmọwe Babajide Martins ni tirẹ sọ fun ile ẹjọ pe wọn ko le ju awọn ẹri naa nu to to meje ti olupẹjọ gbe wa.
















