Gbogbo ìrírí tí mo ní ní ìlú Òyìnbó àti iléeṣẹ́ tí mo dá sílẹ̀ lọ́hùún, mo fẹ́ wá fi darí ìpínlẹ̀ Osun - Olùdíje ADP

Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADP, Kehinde Munirudeen Atanda ti sọ pe gbogbo iriri toun ti ri ko jọ loke okun ni oun yoo lo lati fi tun ipinlẹ Osun ṣe bi oun ba di gomina.
O sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba pe ifẹ ti oun ni si awọn araalu lo mu oun gbe apoti idibo lati di gomina.
"Tẹẹ ba wo bi gbogbo nkan ṣe n lọ ni ilu wa, nkan o lọ bo ṣe lọ bii igba ti awa wa ni kekere ti nkan dara ju bayii lọ".
Oun naa tun mẹnu ba gbogbo iṣoro ti ipinlẹ Osun n koju to fi mọ owo oṣu ti wọn n jẹ awọn oṣiṣẹ to si ni o n ba oun ninu jẹ.
Idi niyi to ni o ka oun lara toun fi fẹ du ipo gomina to si ni awọn o fi iwa nini baba ngbẹjọ ati baba isalẹ sinu aato ẹgbẹ oṣelu tawọn.









