Wo àwọn gbajúgbajà òṣèré tó ti di olóṣèlú

Aworan awon oludije

Oríṣun àwòrán, Google

Bí ètò ìdìbò gbogbogboò ṣe ń súnmọ́ etílé ni àwọn olóṣèlú àti ẹgbẹ́ òṣèlú ní Nàìjíríà máa ń wá àwọn ọ̀nà tí wọn yóò gbà láti jáwé olúborí.

 Bí àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà ṣe ń pòùngbẹ pé kí àwọn ọ̀dọ́ náà gba àkóso orílẹ̀ èdè Nàìjíríà náà ni àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú náà ń wá bí wọn yóò ṣe fa ojú àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra.

 Onírúurú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ló máa ń wáyé nígbà tí ètò ìdìbò bá ti ń bọ̀ lọ́nà tó fi mọ́ kí àwọn olóṣèlú máa lo àwọn òṣèré láti báwọn polongo ètò ìdìbò.

Ní báyìí ó jọ wí pé àwọn gbajúgbajà òṣèré káàkiri Nàìjíríà kò fẹ́ máa ṣe agbẹnusọ fún àwọn olóṣèlú mọ́, àwọn náà ti ń gbégbá ìbò fún ara wọn.

 Bí ètò ìdìbò 2023, ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn òṣèré tíátà ti ń fi èròńgbà láti gbégbá ìbò léde.

Àwọn náà yìí:

Funke Akindele

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni Funke Akindele kéde wí pé òun ni igbákejì olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP.

 Funke Akindele nígbà tó ń kéde ìpinnu rẹ̀ yìí nínú fídíò kan ní òun ti ṣetán láti fi iṣẹ́ òṣèré fún ìgbà díẹ̀ ná kí òun fi gbájúmọ́ òṣèlú.

Desmond Elliot

Sáà kejì tí gbajúgbajà òṣèré yìí ń lò lọ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó nìyí.

 Ní ọdún 2015 ló kọ́kọ́ gbégbá láti dupò láti ṣojú ẹkùn Surulere 1 tó sì jáwé olúborí tí wọ́n sì tún yàn án fún ìgbà kejì.

 Bákan náà ló tún ti rí tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ APC gbà láti lọ ṣojú ẹkùn rẹ̀ fún ìgbà kan si lọ́dún tó ń bọ̀.

Tonto Dikeh

Olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Africa Democratic Congress, ADC, Tonte Ibraye kéde gbajúgbajà òṣèré Tonto Dikeh gẹ́gẹ́ bí igbákejì tí wọ́n yóò jọ máa díje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ náà.

 Ní orí ayélujára tí Tonto Dikeh ti kéde ìyànsípò rẹ̀ ló ti kí olùdíje náà fún bó ṣe ka òun yẹ fún ipò náà.

 Ó ní ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ni yóò jẹ àwọn lógún nínú ìṣèjọba àwọn.

Yul Edochie

Gbajúgbajà òṣèré yìí kéde ìpinnu láti jẹ́ olórí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

 Edochie tó tún jẹ́ ọmọ gbajúgbajà òṣèré Pete Edochie ló ti ń polongo ìpinnu rẹ̀ láti ṣe Ààrẹ Nàìjíríà níbi ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún tó ń bọ̀.

 Ó ní ọwọ́ Ọlọ́run ni èròńgbà òun ọ̀hún wà.

Funke Adesiyan

Ọ̀kan lára àwọn abẹ́ṣinkáwọ́ aya Ààrẹ Muhammadu Buhari, Aisha Buhari ni Funke Adesiyan.

 Ògbóǹtarigì olóṣèlú ni Funke tó ti fìgbà kan jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti APC tó sì ti dupò lọ́kàn ò jọ̀kan.

 Funke Adesiyan kò fi ipò òṣèlú rẹ̀ ṣeré rárá bó ṣe ti fi eré tíátà sílẹ̀ báyìí láti fi gbájúmọ́ òṣèlú.

Ned Nwoko

Bí àwọn òṣèré ṣe ń gbèrò láti ṣe òṣèlú náà ni àwọn ọkọ tàbí aya wọn náà kò kẹ̀rẹ̀ láti fi èròńgbà wọn léde.

 Gbajúgbajà oníṣòwò àti olóṣèlú ni Ned Nwoko tó jẹ́ ọkọ̀ gbajúmọ̀ òṣèré Regina Daniels.

 Nwoko ti rí tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP láti ṣojú ẹkùn àríwá ìpínlẹ̀ Delta ni ile ìgbìmọ̀ aṣòfin, Abuja lọ́dún 2023.

Odi Okojie

Ọkọ gbajúmọ̀ òṣèré Mercy Johnson náà kò gbẹ́yìn láti fi èròńgbà láti ṣojú àwọn ènìyàn rẹ̀ hàn.

 Ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló ti rí tíkẹ́ẹ̀tì láti ṣojú ẹkùn ìlà oòrùn gúúsù àti àríwá Ẹsan, ìpínlẹ̀ Edo ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, Abuja.

 Ní ọdún 2011 ni Odi Okojie àti Mercy Johnson ṣègbéyàwó tí wọ́n sì ti bí ọmọ mẹ́rin.

Oladosu Abiodun Fatomilola

Ọmọ àgbà ọ̀jẹ̀ nínú òṣèré tíátà Yorùbá, Peter Fatomilola ni Oladosu Abiodun Fatomilola.

 Òun ni olùdíje sípò gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria Peoples Party, NNPP ní ìpínlẹ̀ Ekiti níbi ètò ìdìbò to wáyé ní ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹfà ọdún 2022.

 Ó pàdánù ipò náà sọ́wọ́ olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Abiodun Oyebanji.