Àṣírí àwọn ọkùnrin tó ń fi abẹ́rẹ́ pọ́ ikùn ọmọdé síta torí agbe ṣíṣe tú
Wo báwọn ọkùnrin ṣe ń gún ọmọdé ní abẹ́rẹ́ òògùn láti fi wọ́n ṣe agbe lójú pópó

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin
Orisirisi ọgbọn ti awọn onisẹ ibi n da lati gba owo loju popo lo ti n tu sọwọ awọn agbofinro bayii.
Ọpọ igba si ni a maa n ri awọn eeyan to n fi awọn ewe tọrọ owo pe wọn ni arun kan tabi omiran lara.
Amọ ilẹ ti mọ ba afurasi ọdaran kan lara wọn, ti ọwọ ileesẹ ọlọpaa Eko si ti tẹ kẹ, se bi irọ ba lọ titi fun ogun ọdun, ọjọ kan soso ni otitọ yoo ba.
Ikede kan ti agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa fi soju opo ayelujara Twitter rẹ, ti sisọ loju rẹ pe ọwọ oun ti tẹ eeyan mẹrin to n fi awọn ọmọ kekeke tọrọ agbe loju popo.
Ki lo de ti ikun awọn ọmọde ti wọn fi n tọrọ agbe se n wu?
Gẹgẹ bi Benjamin Hundeyin ti wi, kii se pe awọn afurasi naa n fi awọn ọmọde naa, ti wọn to mẹrin se agbe nikan, n se lo tun gun wọn ni abẹrẹ oogun kan.
Abẹrẹ oogun naa ni yoo jẹ ki ikun awọn ọmọde naa wu gbẹndu bii iku alarun, ti yoo si ta sita ringindin bii ẹni to ni arun olokelẹ.
Hundeyin, to fi ikede naa sita lọjọ Abamẹta salaye pe se ni awọn ọkunrin onisẹ ibi naa maa n ko awọn ọmọ ọhun lati abule wa si ilu nla nla lati wa fi wọn se agbe.
O tun salaye pe lẹyin ti wọn ba ko awọn ọmọde naa de aarin igboro, ni wọn yoo wa dokita onisegun oyinbo kan, ti yoo ba wọn gun awọn ọmọde ọhun ni abẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin
Ẹyin obi, ẹ mọ iru ẹni tẹ ko ọmọ yin fun - Ọlọpaa Eko
“Abẹrẹ yii ni yoo jẹ ki ikun wọn wu sita rogodo, ti wọn yoo si maa fi wọn gba owo loju popo pe awọn ọmọ naa n se aisan.
Aanu yoo se awọn eeyan to ba n wo awọn ọmọ naa, ti wọn yoo si maa dawo jọ fun wọn lati fi se itọju wọn.
Amọ ikun yii yoo pada lọ silẹ lẹyin wakati diẹ, ti wọn ba ti sisẹ agbe wọn tan.”
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko wa rọ awọn obi lati maa se akiyesi iru awọn eeyan ti wọn ba n ko ọmọ wọn fun tabi fi wọn sọ.

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ti sọ àrídájú rẹ̀ wí pé dandan ni kí àwọn fìyà tó tọ́ jẹ àwọn tó ṣekúpa ọ̀gá ọlọ́pàá ní ìlú Iganna, ìjọba ìbílẹ̀ Iwajowa ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án.
Nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Oyo, Adewale Osifeso gbé jáde ló ti ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan níbẹ̀.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Oyo, Adebowale Williams tó fajúro sí ìkọlù tí àwọn agbébọn kan ṣe sí àwọn ọlọ́pàá níbi tí DCO àti ọkùnrin kan ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní àwọn méjì mìíràn náà farapa.
Williams ní àwọn méjì tó farapa ọ̀hún ti wà ní ilé ìwòsàn ìjọba kan níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.
Ó ní ìwádìí àwọn ṣàfihàn wí pé àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún ń ṣe iṣẹ́ wọn, gẹ́gẹ́ bí òfin láti máa ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀kadà tí kò bá ní nọ́mbà ìdánimọ̀ lójúnà àti dín ìwà ọ̀daràn kù.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní wí pé ojúṣe àwọn ọlọ́pàá yìí ni wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ ní òpópónà Elejoka-Igangan kí àwọn jàǹdùkú náà tó ṣe ìkọlù sí wọn.
Ó ṣàlàyé pé ìkọlù yìí lọ ṣokùnfà ikú ọ̀gá ọlọ́pàá tó ń mójútó ìwà ọ̀daràn (Divisional Crime Officer, DCO) àti ọkùnrin kan tó wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá nígbà tí wọ́n ń jà fitafita láti rí wí pé àwọn ọ̀daràn náà kò ráyè wọ àgọ́ ọlọ́pàá Iganna.
Bákan náà ló ní DPO àgọ́ ọlọ́pàá náà àti Ìǹsìpẹ́kítọ̀ kan tún fara gbọgbẹ́ àdá èyí tí àwọn ọ̀daràn náà fi ṣá wọn tí wọ́n sì ti wà ní ilé ìwòsàn báyìí níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.
Àtẹ̀jáde náà fi kun pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ti wá ní kí ẹ̀ka tó ń mójútó ìwádìí ìwà ọ̀daràn bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíákíá láti lè tètè fojú àwọn aṣebi náà hàn.
Bákan náà ló ní àwọn ti náwọ́ gán àwọn kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn agbébọn yawọ àgọ́ ọlọ́pàá, pa DCO àti afurasí kan ní Igangan

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Àwọn agbébọn ti tún ṣe ìkọlù sí Igangan, ìjọba ìbílẹ̀ Ibarapa ní ìpínlẹ̀ Oyo.
Ìròyìn tó tẹ BBC News Yorùbá lọ́wọ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá ìlú Igangan ni àwọn agbébọn náà ṣe ìkọlù sí tí wọ́ sì pa ọ̀gá ọlọ́pàá DCO.
Bákan náà ni wọ́n tún pa afurasí kan tó wà ní àhámọ́ àgọ́ ọlọ́pàá náà.
Ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹsàn-án ni ìkọlù náà wáyé.
Bákan náà ni ìròyìn ní DPO, Ìǹsìpẹ́kítọ̀ ti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀hún náà fara gbọta.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo, Adewale Osifeso fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ fún BBC ní òwúrọ̀ ọjọ́rú.
Osifeso ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí àwọn yóò sì fi ohun tí àwọn bá bábọ̀ léde.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn ń bọ̀ láìpẹ́.















