Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tẹ̀lẹ̀ fún gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun di èrò ẹ̀wọ̀n ní US fún jìbìtì

Oríṣun àwòrán, Abidemi Rufai/facebook
Ile ẹjọ kan ni orilẹ-ede America, ti ju amugbalẹgbẹ nigba kan fun gomina ipinlẹ Ogun, Abidemi Rufai si ẹwọn ọdun marun-un.
Akọsilẹ ẹsun ti wọn fi kan Rufai fihan pe ni ọdun 2017, o jí akọsilẹ nipa ọmọ orilẹ-ede America to le ni ẹgbẹrun lọna ogún, to si fi beere fun owo to le miliọnu meji Dọla lọwọ ijọba.
Nkan ti ọgbẹni Rufai sọ fun ijọba ni pe oun yoo fi ṣe owo itunu fun awọn eeyan naa.
O si le ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Dọla ti ileeṣẹ ijọba kọọkan to da si ọrọ naa san fun.
Yatọ si ti ọdun 2017, o tun beere fun owo iranwọ lọwọ ijọba lasiko ajakalẹ aarun Covid-19, ti wọn si san owo to to 350,763 Dọla si awọn apo asunwọn to wa ni abẹ akoso Rufai.
Ọna wo ni Rufai fi gba to $600,000 lọwọ ijọba America
Awọn alaṣẹ sọ pe Rufai lo akọsilẹ ati aworan eeyan to le ni ọgọrun nilu Washington, lati beere fun iranlọwọ owo ti ijọba fun awọn ti ajakalẹ aarun Covid-19 gba iṣẹ lọwọ wọn.
Bẹẹ naa lo tun sẹ ni awọn ilu bi Hawaii, Wyoming, Massachusetts, Montana, New York, ati Pennsylvania.
Niṣe lo fi imeeli ọtọọtọ fi iwe ẹ̀bẹ̀ ranṣẹ, ki wọn o ma ba mọ pe ẹnikan pere lo n kọ gbogbo rẹ.
Awọn apo asunwọn ori ayelujara si lo fi gba owo naa. Koda, wọn ni o fi owo naa ranṣẹ diẹdiẹ si adirẹsi awọn mọlẹbi rẹ to n gbe ni New York ati Jamaica ati apo asunwọn miran to jẹ tiẹ nilẹ America.
Agbẹjro ijọba to rojọ tako o, Cindy Chang, sọ pe eeyan 238 to nilo iranlọwọ, ni Rufai fi iwa jibiti rẹ ba aye wọn jẹ.
Lati oṣu Karun-un, ọdun 2021 ni Rufai ti wa ni ahamọ awọn agbofinro nigba ti ọwọ tẹ ẹ ni papakọ ọkọ ofurufu JFK ni new York.












