A kò tako Tinubu, kó ṣàá má díwa lọ́wọ́ ìpolongo Yoruba Nation - Akintoye

Olori ẹgbẹ to n polongo fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, Ọjọgbọn Banji Akintoye, ti sọ pe awọn ko nii ti tori pe ọmọ Yoruba kankan n dije fun ipo aarẹ, jawọ ninu ijijagbara awọn.
Ọjọgbọn Akintoye sọ ọrọ naa ninu ifọrọwanilẹnu wo kan pẹlu BBC.
O sọ eyi ni idahun si ibeere pe ṣe ẹgbẹ naa yoo ṣe atilẹyin fun Bola Tinubu, ọkan lara awọn ọmọ Yoruba to n dije fun ipo aarẹ lọdun 2023.
Akintoye ni, kii ṣe nkan to buru pe ọmọ Yoruba n dije, ni wọn igba ti awọn ṣi wa ni Naijiria, o ni amọ tiẹ ko nii di awọn lọwọ ipolongo, bẹẹ ni awọn ko nii fi ipolongo di i lọwọ.
O ṣalaye pe awọn to fẹ orilẹ-ede Oduduwa lo pọ ju laarin awọn ọmọ Yoruba, "nitori naa, a ko nii dakẹ.
"A ti ba ipolongo wa de ipele to ga julọ, eyi to jẹ fifi to awọn awujọ agbaye to le gba orilẹ-ede wa fun wa, leti.
Ọrọ ti Akintoye sọ waye lasiko ti awọn ọmọ Yoruba kan ninu Afenifere sọ pe oludije lati ẹya Igbo, Peter Obi ni awọn ṣe atilẹyin fun.
Amọ awọn kan lara wọn tun sọ pe Tinubu ni awọn n ba lọ.



