'Bí ọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní dàrú ní Naijiria rèé ...'
'Bí ọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní dàrú ní Naijiria rèé ...'

Aarẹ akọkọ fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lapapọ lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Hassan Adebayo Sunmọnu ti sọ bi eto ọrọ aje orilẹede Naijiria ṣe wọ wa lati ibẹrẹ.
Ọgbẹni Sunmọnu lasiko ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ BBC News Yoruba ni ikọ ologun to gba ijọba ni Naijiria lo ba ọrọ aje Naijiria.
Ninu ọrọ rẹ, o ni eto iṣejọba Naijiria ki awọn ologun to gbajọba fi aye silẹ ni awọn ipinlẹ fun idagbasoke eto ọrọ aje wọn
Amọ o ni kete ti awọn ologun gbajọba ni wọn kede pe ohun gbogbo to niiṣe pẹlu eto ẹkọ, ilera ati ọrọ aje ti da ti ijọba apapọ.
Bakan naa lo ni ijọba ologun to sọ ipinlẹ mẹta da ipinlẹ mejidinlogun ni wọn bẹrẹ si ni fi owo Naijiria tọju awọn oloṣelu.
Ẹkunrẹrẹ fidio naa wa nibi.






