Ó lé ní 1,500 ọmọdé tí mo ti fi èdè Yorùbá kọ́ ní 'Software Development' lọ́fẹ̀ẹ́

Yoruba ni 'ẹyin lo n di akukọ'.
Bẹẹ ni ọrọ ri fun ọdọmọkunrin kan, Abass Oyeyemi to n fi ede Yoruba kọ awọn ọmọde ni imọ ijinlẹ kọmputa ti wọn n pe ni 'software development'.
Ọgbẹni Oyeyemi ṣe idasilẹ ile ẹkọ kan, eyi to pe ni Teki Site, nibi ti oun ati awọn ọrẹ rẹ kan ti n lọ kaakiri ilu lati kọ awọn ọmọde.
O ni oun da ile ẹkọ imọ ayelujara naa silẹ, nitori ki awọn ọmọ naa ma ba ya iyakuya, tabi gbọ ẹkọ odi to le mu wọn wọ iṣẹ jibiti ori ayelujara ati awọn iwa buruku miran to le ba ọjọ iwaju wọn jẹ.
Oyeyemi ṣalaye fun BBC pe ikọ oun ti si awọn ilu kaakiri ilẹ Yoruba, ti wọn si ti kọ ọmọ to le ni ẹgbẹrun kan aabọ.
"Lootọ ede Gẹẹsi ni imọ kọmputa, amọ a kiyesi pe awọn ọmọ to wa ni igberiko ni a n kọ. Nitori ki ẹkọ naa le tete ye wọn la ṣe n lo ede abinibi.



